Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Ẹranko Ẹhànnà Aláwọ̀ Rírẹ̀dòdò Tó Wà Nínú Ìṣípayá orí Kẹtàdínlógún?

Kí Ni Ẹranko Ẹhànnà Aláwọ̀ Rírẹ̀dòdò Tó Wà Nínú Ìṣípayá orí Kẹtàdínlógún?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tá a ṣàpèjúwe nínú Ìṣípayá orí kẹtàdínlógún ń ṣàpẹẹrẹ àjọ kan tó ń ṣojú fún ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ète wọn ni láti mú kí gbogbo ìjọba ayé wà níṣọ̀kan. Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lorúkọ àjọ yìí tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ló ń jẹ́.

Àwọn àmì tá a lè fi dá ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà mọ̀

  1.   Ètò òṣèlú. Ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò yìí ní “orí méje” tó túmọ̀ sí “òkè ńlá méje” àti “Ọba méje,” tàbí agbára òṣèlú. (Ìṣípayá 17:9, 10) Bíbélì sábà máa ń fi òkè ńlá àti ẹranko ẹhànnà ṣàpẹẹrẹ àwọ́n ìjọba ayé.​—Jeremáyà 51:24, 25; Dáníẹ́lì 2:44, 45; 7:17, 23.

  2.   Ó jọ ètò ìṣèlú àgbáyé. Ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò yìí jọ ẹranko ẹhànnà tí Ìṣípayá orí kẹtàlá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, èyí tó ń ṣàpẹẹrẹ ètò ìṣèlú àgbáyé. Àwọn ẹranko ẹhànnà méjèèjì ní orí méje, ìwo mẹ́wàá, àti àwọn orúkọ tí ó kún fún ọ̀rọ̀ òdì. (Ìṣípayá 13:1; 17:3) Àwọn ìjọra yìí ṣe kedere tó fi jẹ́ pé kò kan lè ṣàdédé wà. A jẹ́ pé ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò yìí jẹ́ àwòrán ètò ìṣèlú àgbáyé.​—Ìṣípayá 13:15.

  3.   Agbára látọ̀dọ̀ àwọn alákòóso míì. Ọ̀dọ̀ àwọn alákòóso tó lágbára ni ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò yẹn ti “jáde wá,” tàbí lédè míì ibẹ̀ ló ti ń gba agbára.​—Ìṣípayá 17:11, 17.

  4.   Ó máa ń bá àwọn onísìn da nǹkan pọ̀. Bábílónì Ńlá, ìyẹn ìparapọ̀ ìsìn èké àgbáyé jókòó lórí ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà. Èyí fi hàn pé ẹranko ẹhànnà náà ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn onísìn.​—Ìṣípayá 17:3-5.

  5.   Kò bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run. Ẹranko ẹhànnà náà “kún fún àwọn orúkọ ọ̀rọ̀ òdì.”​—Ìṣípayá 17:3.

  6.   Kò ní sí mọ́ fún ìgbà díẹ̀. Ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò yìí máa wà nínú “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀,” a tàbí lédè míì kò ní sí fún sáà àkókò kan, àmọ́ ó máa tún pa dà wà lẹ́ẹ̀kan si.​—Ìṣípayá 17:8.

Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ní ìmúṣe

 Ẹ jẹ́ ká wo bí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti àjọ tó kọ́kọ́ wà ṣáájú rẹ̀, ìyẹn Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà ṣẹ.

  1.   Ètò òṣèlú. Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ń ṣètìlẹyìn fún ètò ìṣèlú nípa gbígbé “ìlànà orí-ò-jorí kalẹ̀ fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀.” b

  2.   Ó jọ ètò ìṣèlú àgbáyé. Ní ọdún 2011, Orílé-èdè kan kún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Èyí mú kí orílé-èdè tó wà lábẹ́ wọn di igba ó dín méje [193]. Fún ìdí yìí, wọ́n gbà pé àwọn ń ṣojú fún èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn orílẹ̀-èdè àti gbogbo èèyàn kárí ayé.

  3.   Agbára látọ̀dọ̀ àwọn alákòóso míì. Àwọn orílẹ̀-èdè tó kóra jọ ló dá àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè yìí sílẹ̀, ìwọ̀nba agbára àti àṣẹ tí wọ́n bá sì fún un ló máa ní.

  4.   Ó máa ń bá àwọn onísìn da nǹkan pọ̀. Gbogbo ìgbà ni Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ń rí àtìlẹ́yìn látọ̀dọ̀ àwọn onísìn. c

  5.   Kò bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run. Wọ́n dá Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ láti mú kí “àlááfíà àti ààbò wà kárí ayé.” d Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lọ́kàn tiwọn ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe dáa, síbẹ̀ àjọ yìí ò fọ̀wọ̀ hàn fún Ọlọ́run torí pé wọ́n láwọn lè ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ pé Ìjọba òun nìkan ló máa ṣe.​—Sáàmù 46:9; Dáníẹ́lì 2:44.

  6.   Kò ní sí mọ́ fún ìgbà díẹ̀. Wọ́n dá àjọ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ kété lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kìíní parí kó lè mú kí àlááfíà wà kárí ayé. Àmọ́, àjọ yìí kò rí nǹkan kan ṣe sí rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé. Ńṣe ni àjọ yìí kógbá wọlé nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1939. Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì lọ́dún 1945, wọ́n dá àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀. Ìdí tí wọ́n fi dá a sílẹ̀ àti ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣètò rẹ̀ fara jọ ti àjọ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè.

a Ìwé Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words sọ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀” ń ṣàpèjúwe “kòtò tí kò ní ìsàlẹ̀.” Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀ pè é ní “ọ̀gbun jíjìn.” Ohun tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí nínú Bíbélì ni ipò àìlè ṣe ohunkóhun, á wá dà bí ẹni tí kò lè ṣe nǹkan kan.

b Wo Àpilẹ̀kọ kejì nínú ìwé àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè.

c Bí àpẹẹrẹ, ìgbìmọ̀ tó ń ṣojú fún àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kéde lọ́dún 1918 pé Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ló máa di “ètò ìṣèlú tí Ọlọ́run máa lò láti ṣèjọba lórí ilẹ̀ ayé.” Lọ́dún 1965, àwọn tó ń ṣojú fún ìsìn Búdà, ẹ̀sìn Kátólíìkì, ẹ̀sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, ẹ̀sìn Híńdù, Ìsìláàmù, ẹ̀sìn àwọn Júù, àti Pùròtẹ́sítáǹtì pé jọ sí ìlú San Francisco láti gbàdúrà fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, kí wọ́n sì tì í lẹ́yìn. Bákan náà lọ́dún 1979, Póòpù John Paul Kejì sọ pé òun ní ìrètí pé àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ló máa mú kí àlááfíà àti ìdájọ́ òdodo fẹsẹ̀ múlẹ̀.”

d Wo Àpilẹ̀kọ kìíní nínú ìwé àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè.