Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Bíbélì

Ìpelẹ̀ṣẹ̀

Kí Ni Bíbélì?

Bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò tó lárinrin lọ sínú Bíbélì tí í ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Ṣé Ọgbọ́n Èèyàn Ni Wọ́n Fi Kọ Bíbélì?

Gbọ́ ohun tí Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ.

Ṣé Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì Ti Wá?

Ọ̀pọ̀ àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ló darí àwọn láti kọ́ ohun táwọn kọ. Kí nìdí?

Ṣé Mósè Ló Kọ Bíbélì?

Mósè wà lára àwọn tó kọ Bíbélì. Èèyàn mélòó ló kọ Bíbélì?

Ǹjẹ́ A Lè Mọ Ẹni Tó Kọ Bíbélì?

Àwọn tó kọ Bíbélì gbà pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ti wá àti pé Ọlọ́run ló darí àwọn. Kí nìdí tí a fi lè gba ohun tí wọ́n kọ gbọ́?

Ṣé Wọ́n Ti Yí Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì Pa Dà?

Torí pé ó pẹ́ gan-an tí Bíbélì ti wà, kí ló lè jẹ́ kó dá wa lójú pé ohun tó wà nínú ẹ̀ ò yí pa dà?

Ìgbà Wo Ni Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Dá Àgbáálá Ayé?

Tá a bá mọ bí Jẹ́nẹ́sísì ṣe lo àwọn ọ̀rọ̀ náà “ìbẹ̀rẹ̀” àti “ọjọ́” lá to lè dáhùn.

Ṣé Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Bá Ohun Tí Bíbélì Sọ Mu?

Ṣé àwọn ohun tí kì í ṣe òótọ́ nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì wà nínú Bíbélì?

Ṣé Bíbélì Fi Kọ́ni Pé Ayé Rí Pẹrẹsẹ?

Ṣé ọ̀rọ̀ inú ìwé tó ti pẹ́ yìí péye?

Ṣé Ìwé Àwọn Aláwọ̀ Funfun Ni Bíbélì?

Ibo ni wọ́n ti bí àwọn tó kọ Bíbélì, apá ibo láyé ni wọ́n ti wá?

Ìgbà Wo Ni Wọ́n Kọ Ìtàn Jésù?

Báwo ló ṣe pẹ́ tó lẹ́yìn tí Jésù kú kí wọ́n tó kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere?

Bá A Ṣe Lè Ka Bíbélì Ká sì Lóye Rẹ̀

Kí Ló Yẹ Kí O Ṣe Kó O Lè Lóye Bíbélì?

O lè lóye ọ̀rọ̀ pàtàkì tó wà nínú ẹ̀.

Ṣé Bíbélì Ta Kora?

Ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó ta kora nínú Bíbélì àtàwọn ìlànà tó o lè tẹ̀lé tá á jẹ́ kó o lóye ohun tí wọ́n túmọ̀ sí dáadáa.

Kí Là Ń Pè Ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

Ọ̀rọ̀ náà ní ju ìtumọ̀ kan lọ nínú Bíbélì.

Kí Ni Ìtumọ̀ “Ojú fún Ojú”?

Ṣé òfin “ojú fún ojú” fún àwọn èèyàn láṣẹ láti gbẹ̀san ara wọn?

Kí Ni Òfin Mẹ́wàá Tó Wá Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?

Àwọn wo ni Ọlọ́run fún ní òfin yìí? Ṣé ó di dandan káwọn Kristẹni máa tẹ̀ lé e?

Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Jẹ́ “Aláàánú Ará Samáríà”?

Jésù fọgbọ́n lo ìtàn yìí láti kọ́ àwọn èèyàn nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe sí àwọn míì láìka irú ẹni tí wọ́n jẹ́, ẹ̀yà wọn àti orílẹ̀-èdè wọn sí.

Kí Ló Ń Jẹ́ Tórà?

Ta ló kọ ọ́? Ṣé ẹ̀kọ́ tó máa wà pẹ́, tá ò gbọ́dọ̀ pa tì ló wà nínú rẹ̀?

Àsọtẹ́lẹ̀ àti Ohun Tó Ṣàpẹẹrẹ

Kí Ni Àsọtẹ́lẹ̀?

Ṣé gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló dá lórí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú? Kì í ṣe gbogbo ẹ̀.

Kí Ní Ìtumọ̀ Àwọn Nọ́ńbà Tí Bíbélì Lò? Ǹjẹ́ Fífi Nọ́ńbà Sọ Ìtumọ̀ Nǹkan Bá Bíbélì Mu?

Wo àwọn nọ́ńbà tí wọ́n fi ṣàpẹẹrẹ nínú Bíbélì, kí o sì wo bó ṣe yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe máa ń fi nọ́ńbà sọ ìtumọ̀ nǹkan.

Kí Ni Àwọn Ìtàn Inú Bíbélì Tó Tẹ̀ Léra Fi Hàn Nípa Ọdún 1914?

Àsọtẹ́lẹ̀ tó dá lórí “ìgbà méje” inú ìwé Dáníẹ́lì orí kẹrin tọ́ka sí àkókò tí ìṣàkóso ẹ̀dá èèyàn máa dópin.

Kí Làwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìṣípayá Túmọ̀ Sí?

Ìwé yìí fúnra rẹ̀ sọ pé aláyọ̀ ni ẹni tó bá ń ka ọ̀rọ̀ inú rẹ̀, tó lóye rẹ̀, tó sì ń pa á mọ́.

Kí Ni Jerúsálẹ́mù Tuntun?

Báwo ni ọ̀rọ̀ ìlú tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí ṣe kàn ọ́?

Kí Ni Ẹranko Ẹhànnà Olórí Méje Inú Ìṣípayá Orí Kẹtàlá Dúró Fún?

Ẹranko ẹhànnà náà ní ọlá àṣẹ, ó ní agbára, ó sì ní ìtẹ́ kan. Kí tún ni àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn wá?

Kí Ni Ẹranko Ẹhànnà Aláwọ̀ Rírẹ̀dòdò Tó Wà Nínú Ìṣípayá orí Kẹtàdínlógún?

Ohun mẹ́fà tó máa jẹ́ ká mọ ohun tí ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò inú Ìṣípayá orí 17.

Kí Ni Nọ́ńbà Náà 666 Túmọ̀ Sí?

Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tí nọ́ńbà náà 666 àti àmì ẹranko ẹhànnà náà túmọ̀ sí.

Kí Ni Bábílónì Ńlá?

Bíbélì sọ pé ìlú ni, ó sì tún pè é ní aṣẹ́wó.

Ta Ni Ọkùnrin Ọlọ́rọ̀ Náà àti Lásárù?

Ṣé àkàwé Jésù yìí fi hàn pé àwọn ẹni rere máa lọ sọ́run, àwọn èèyàn burúkú sì máa joró nínú iná ọ̀run àpáàdì?

Òpin Ayé

Àwọn Àmì Wo Ló Fi Hàn Pé A Ti Wà Ní “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn,” Tàbí “Òpin Ayé”?

Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ni Bíbélì sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé a ti wà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn.

Ṣé Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Bí Àwọn Èèyàn Á Ṣe Máa Hùwà Lónìí?

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ìwà àwọn èèyàn á máa burú sí i.

Kí Ni Ìpọ́njú Ńlá?

Ohun táwọn èèyàn ń pè ní ‘àsọtẹ́lẹ̀ àkókò òpin’ jẹ́ ká mọ nípa ìgbà tí nǹkan máa nira jù lọ fún aráyé. Kí la retí pé ó máa ṣẹlẹ̀?

Kí Ni Ogun Amágẹ́dọ́nì?

Ẹ̀ẹ̀kan péré ni ọ̀rọ̀ náà Amágẹ́dọ́nì fara hàn nínú Bíbélì, àmọ́ Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ gan-an nípa ogun tí ọ̀rọ̀ náà tọ́ka sí.

Ṣé Ilẹ̀ Ayé Máa Pa Run?

Ohun tí Bíbélì sọ lè yà ọ́ lẹ́nu.

Ìgbà wo ni òpin ayé máa dé?

Ṣé Bíbélì sọ ìgbà tó máa dé gan-an?

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe?

Kọ́ nípa ohun tó máa wáyé nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso gbogbo aye.

Àwọn Èèyàn, Ibi àti Àwọn Nǹkan

Àwọn Obìnrin inú Bíbélì​—Kí La Rí Kọ́ Lára Wọn?

Wo ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn obìnrin rere tí Bíbélì mẹ́nu kàn àtàwọn obìnrin búburú tó ṣe ohun tí kò dáa.

Ṣé Màríà Ni Ìyá Ọlọ́run?

Ìwé Mímọ́ àti ìtàn ẹ̀sìn Kristẹni sọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa ẹ̀kọ́ yìí.

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Màríà Wúńdíá?

Àwọn kan sọ pé wúńdíá tó bí Jésù kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀. Ṣé Bíbélì jẹ́rìí sí i pé bẹ́ẹ̀ ló rí?

Ta Ni Jòhánù Arinibọmi?

Àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ múra ọkàn àwọn Júù bíi tiẹ̀ sílẹ̀ kí wọ́n lè dá Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí mọ̀.

Ta Ni Màríà Magidalénì?

Díẹ̀ lára ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ nípa Màríà kò bá Bíbélì mu.

Àwọn Wo Ni “Amòye Mẹ́ta Náà”? Ṣé “Ìràwọ̀” Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Ni Wọ́n Tẹ̀ Lé?

Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó gbajúmọ̀ tí wọ́n máa ń sọ nígbà Kérésìmesì ni kò sí nínú Bíbélì.

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Dáníẹ́lì?

Ọlọ́run fi àwọn ìran kan hàn án nípa àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí.

Ta Ni Ìyàwó Kéènì?

Tá a bá ronú lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, a máa rí ìdáhùn tó tẹ́ wa lọ́rùn sí ìbéèrè yìí.

Ṣé Ìtàn Àròsọ Lásán Ni Ìtàn Nóà àti Ìkún Omi?

Bíbélì sọ pé ìgbà kan wà tí Ọlọ́run mú kí ìkún omi ńlá kan ṣẹlẹ̀, kó lè fi pa àwọn èèyàn burúkú rún. Àwọn ẹ̀rí wo ló wà nínú Bíbélì tó jẹ́ ká gbà pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Ìkún Omi náà ti wá lóòótọ́?

Kí Ni Àpótí Májẹ̀mú?

Ọlọ́run ló pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe àpótí yìí láyé àtijọ́. Kí ló wà fún?

Ṣé Aṣọ Ìsìnkú Turin Ni Wọ́n Fi Sin Òkú Jésù?

Kókó pàtàkì mẹ́ta nípa Aṣọ Ìsìnkú náà jẹ́ ká mọ ìdáhùn.

Ṣé Ẹfolúṣọ̀n Ni Ọlọ́run Lò Láti Dá Àwọn Nǹkan?

Kò si ibì kankan tí Bíbélì ti tako àwọn ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ǹsì pé àwọn ìyàtọ̀ máa ń wà nínú onírúurú ìṣẹ̀dá.

Ọgbọ́n Tó Wúlò

Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Ní Ìdílé Aláyọ̀?

Ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n láti inú Bíbélì ti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin lọ́wọ́ láti ní ìdílé aláyọ̀.

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ọ̀rẹ́?

Àwọn ọ̀rẹ́ gidi máa ń jẹ́ ká níwà tó dáa. Fọgbọ́n yan àwọn ọ̀rẹ́ rẹ!

Kí Ni Òfin Oníwúrà?

Nígbà tí Jésù fún wa ní Òfin Oníwúrà, gbogbo èèyàn ló ní lọ́kàn pé ká máa ṣoore fún títí kan àwọn ọ̀tá wa.

Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti ‘Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ọ̀tá Wa’?

Kò rọrùn láti fi ọ̀rọ̀ tó ṣe kedere, tó sì nítumọ̀ tí Jésù sọ sílò.

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣe Ìpinnu Tó Mọ́gbọ́n Dání?

Ohun mẹ́fà tí Bíbélì sọ pé o lè ṣe kó o lè ní ọgbọ́n àti òye.

Kí Ló Lè Fún Mi Ní Ìrètí?

Orísun ìrètí tó ṣeé gbára lé máa jẹ́ kí ayé rẹ dára sí i nísinsìnyìí, ó sì máa jẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la rẹ dájú.

Ṣé Owó Ni Gbòǹgbò Ohun Búburú Gbogbo?

Àwọn èèyàn sábà máa ń sọ pé “owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo” àmọ́ kì í ṣe bí Bíbélì ṣe sọ ọ́ nìyẹn.

Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mo Bá Ní Ìṣòro Owó Tàbí Ti Mo Bá Jẹ Gbèsè?

Ti pé èèyàn ní owó kò sọ pé kó ní ayọ̀, àmọ́ àwọn ìlànà Bíbélì mẹ́rin kan yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti bójú tó ọ̀rọ̀ owó.

Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mo Bá Ń Ṣàìsàn Ọlọ́jọ́ Pípẹ́?

Bẹ́ẹ̀ ni! Kọ́ nípa ohun mẹ́ta tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́.

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Gbígbẹ̀san?

Ìmọ̀ràn Bíbélì ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti borí ẹ̀mí gbígba ẹsan.

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìbínú?

Ṣé ó tọ́ kéèyàn bínú rárá? Kí ló yẹ kó o ṣe tí ìbínú ẹ bá ti ń le?

Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mo Bá Ní Ìrẹ̀wẹ̀sì Ọkàn?

Àwọn ohun mẹ́ta kan wà tí Ọlọ́run máa ń fún wa ká lè fara da ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn.

Bí Ìgbésí Ayé Mi Ṣe Rí Kò Mú Inú Mi Dùn, Ṣé Ìsìn, Ọlọ́run Tàbí Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?

Kọ́ nípa bí ìgbésí ayé rẹ ṣe lè sunwọ̀n sí i nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú tó o bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run.

Ṣé Ó Dáa Téèyàn Bá Nífẹ̀ẹ́ Ara Rẹ̀?

Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”