Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Nìdí Táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Ṣe Àwọn Ayẹyẹ Kan?

Kí Nìdí Táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Ṣe Àwọn Ayẹyẹ Kan?

 Báwo ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe máa ń mọ̀ bóyá inú Ọlọ́run dùn sí ayẹyẹ kan tàbí kò dùn?

 Kí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó pinnu bóyá ká ṣe ayẹyẹ kan tàbí ká má ṣe é, a máa kọ́kọ́ wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀. Kò sí àní-àní pé àwọn ayẹyẹ kan ta ko ìlànà Bíbélì. Torí náà, tí ayẹyẹ kan bá ta ko ìlànà Bíbélì, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò ní ṣe é. Àmọ́ tó bá kan àwọn ayẹyẹ míì, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa pinnu ohun táá ṣe kó lè ‘ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ níwájú Ọlọ́run àti èèyàn’​—Ìṣe 24:16.

 Àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń bi ara wa ká tó pinnu bóyá a máa ṣe ayẹyẹ kan àbí a ò ní ṣe é. a

  •   Ṣé ẹ̀kọ́ tí kò bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu ló bí ayẹyẹ náà?

     Ìlànà Bíbélì: “‘Ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ mọ́.’”​—2 Kọ́ríńtì 6:​15-17.

     Káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè yẹra pátápátá fún àwọn ẹ̀kọ́ tó lè sọ wa di aláìmọ́ lójú Ọlọ́run, ìyẹn àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá Bíbélì mu, a kì í ṣe àwọn ayẹyẹ tó jẹ mọ́ àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí.

     Ayẹyẹ tó ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ọlọ́run míì tàbí tó gba pé kéèyàn nígbàgbọ́ tàbí jọ́sìn òrìṣà. Jésù sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.” (Mátíù 4:​10) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fi ìlànà yìí sọ́kàn, ìdí nìyẹn tá ò kì í ṣe Kérésìmesì, ọdún Àjíǹde tàbí èyí tí wọ́n ń pè ní May Day, torí pé ọ̀dọ̀ àwọn tó ń bọ̀rìṣà ló ti ṣẹ̀ wá, kì í ṣe ọ̀dọ̀ Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, a kì í ṣe àwọn ayẹyẹ tó tẹ̀ lé e yìí.

    •  Kwanzaa. Orúkọ náà Kwanzaa “wá láti inú ọ̀rọ̀ kan lédè Swahili, ìyẹn matunda ya kwanza, tó túmọ̀ sí ‘àkọ́so,’ èyí fi hàn pé, inú àjọ̀dún ìkórè àkọ́kọ́ tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú ìtàn àwọn ará Áfíríkà ni ayẹyẹ náà ti ṣẹ̀.” (Encyclopedia of Black Studies) Àwọn kan sọ pé ọdún Kwanzaa kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìjọsìn, síbẹ̀ ìwé Encyclopedia of African Religion fi ayẹyẹ náà wé àjọ̀dún tí àwọn ará Áfíríkà máa ń ṣe, tí wọ́n máa ń fi àkọ́so èso “ta àwọn òrìṣà àtàwọn baba ńlá wọn lọ́rẹ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn.” Ó tún sọ pé: “Ìdí yìí kan náà làwọn ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà tó jẹ́ adúláwọ̀ fi ń ṣe ọdún Kwanzaa, kí wọ́n lè dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn baba ńlá wọn kí wọ́n sì ta wọ́n lọ́rẹ torí bí wọ́n ṣe dá ẹ̀mí wọn sí.”

      Ayẹyẹ Kwanzaa

    •  Mid-Autumn. Wọ́n máa ń fi ayẹyẹ yìí júbà “abo ọlọ́run oòrùn.” (Holidays, Festivals, and Celebrations of the World Dictionary) Lásìkò ayẹyẹ yìí, wọ́n máa ń ṣe ètùtù kan tí “àwọn ìyàwó ilé á máa tẹrí ba fún òrìṣà, àṣà yìí làwọn ará Ṣáínà ń pè ní kowtow.”​—Religions of the World​​—A Comprehensive Encyclopedia of Beliefs and Practices.

    •  Nauruz (Nowruz). “Inú ìsìn Zoroaster ni apá mélòó kan lára ayẹyẹ yìí ti ṣẹ̀ wá, wọ́n sì gbà pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọjọ́ mímọ́ jù lọ nínú kàlẹ́ńdà àwọn onísìn Zoroaster látijọ́. . . . Wọ́n sọ pé tó bá dìgbà òtútù, ńṣe ni Spirit of Winter, tí wọ́n kà sí ọlọ́run òtútù máa ń gbá Spirit of Noon [tàbí Rapithwin], tí wọ́n kà sí ọlọ́run ẹ̀ẹ̀rùn wọlẹ̀. Tó bá wá di ọ̀sán ọjọ́ tí wọ́n ń ṣe ọdún Nowruz, tìlù-tìfọn ni wọ́n fi máa ń kí Spirit of Noon káàbọ̀ pa dà ní ìbámu pẹ̀lú àṣà àwọn onísìn Zoroaster.”​—United Nations Educational, Scientific and Cultural Organization.

    •  Shab-e Yalda. Ìwé kan tó ń jẹ́ Sufism in the Secret History of Persia sọ ohun kan nípa ayẹyẹ yìí, èyí tí wọ́n máa ń ṣe nígbà òtútù. Ó ní, “kò sí àní-àní pé ayẹyẹ yìí ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìjọsìn òrìṣà Mithra,” tí wọ́n kà sí òrìṣà ìmọ́lẹ̀. Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé ayẹyẹ náà jọra pẹ̀lú ọlọ́run oòrùn tí àwọn ará Róòmù àti Gíríìkì máa ń bọ. b

    •  Ìdúpẹ́. Bíi ti ayẹyẹ Kwanzaa, inú ọdún ìkórè tí wọ́n fi ń júbà onírúurú ọlọ́run láyé àtijọ́ ni ayẹyẹ ìdúpẹ́ ti wá. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, “wọ́n mú àwọn àṣà àtijọ́ yìí wọnú ẹ̀sìn Kristẹni”​—A Great and Godly Adventure​—The Pilgrims and the Myth of the First Thanksgiving.

     Ayẹyẹ tó dá lórí àwọn nǹkan tí kò jóòótọ́ tàbí tó mú kéèyàn gbà gbọ́ nínú oríire. Bíbélì sọ pé àwọn “tó ń tẹ́ tábìlì fún ọlọ́run Oríire” wà “lára àwọn tó ń fi Jèhófà sílẹ̀.” (Àìsáyà 65:11) Nítorí bẹ́ẹ̀, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe àwọn ayẹyẹ tó tẹ̀ lé e yìí:

    •  Ivan Kupala. Ìwé The A to Z of Belarus sọ pé “ọ̀pọ̀ ló gbà pé lọ́jọ́ tí wọ́n bá ń ṣe ayẹyẹ Ivan Kupala, agbára abàmì kan máa ń jáde lára ìṣẹ̀dá, ẹni tó bá nígboyà tó sì jẹ́ olóríire nìkan ló ń rí gba agbára yìí lò.” Ní ìbẹ̀rẹ̀, àwọn abọ̀rìṣà ló máa ń ṣe ọdún yìí láti fi ṣe ayẹyẹ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. Àmọ́, ìwé Encyclopedia of Contemporary Russian Culture sọ pé, “lẹ́yìn táwọn abọ̀rìṣà kan di Kristẹni, wọ́n mú àṣà yìí wọnú ṣọ́ọ̀ṣì, ó sì di àjọ̀dún táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fi ń ṣàyẹ́sí Jòhánù Oníbatisí.”

    •  Ọdún Tuntun (ìyẹn Chinese New Year tàbí Korean New Year). “Lásìkò tí wọ́n [àwọn ará Ṣáínà] bá ń ṣe ayẹyẹ ọdún tuntun yìí, ohun táwọn ìdílé, ẹbí àti ọ̀rẹ́ máa ń kà sí pàtàkì jù lọ ni bí wọ́n ṣe máa ṣoríire àti bí wọ́n ṣe máa tu àwọn òrìṣà àtàwọn ẹ̀mí àìrí lójú. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún máa ń kí ara wọn pé ọdún á yabo, àṣèyí-ṣàmọ́dún.” (Mooncakes and Hungry Ghosts—Festivals of China) Lọ́nà kan náà, táwọn ará Korea bá ń ṣe ayẹyẹ ọdún tuntun wọn, wọ́n máa ń rúbọ sáwọn baba ńlá wọn, wọ́n máa ń ṣe ètùtù láti lé àwọn ẹ̀mí èṣù dà nù kí wọ́n lè ṣoríire lọ́dún tuntun, lẹ́yìn náà, wọ́n tún máa ń woṣẹ́ kí wọ́n lè mọ bí ọdún tuntun náà ṣe máa rí.”​—Encyclopedia of New Year’s Holidays Worldwide.

      Ayẹyẹ Chinese New Year

     Ayẹyẹ tó dá lórí èrò pé ọkàn èèyàn kì í kú. Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé ọkàn èèyàn máa ń kú. (Ìsíkíẹ́lì 18:4) Nítorí náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe àwọn ayẹyẹ tó tẹ̀ lé e yìí, torí pé wọ́n ń mú káwọn èèyàn gbà pé ọkàn èèyàn kì í kú:

    •  Ọjọ́ àwọn Òkú. Ìwé New Catholic Encyclopedia sọ pé ọjọ́ yìí ni wọ́n máa fi ń “rántí gbogbo àwọn olóòótọ́ tó ti kú. Láwọn ọdún 500 sí 1500 Sànmánì Kristẹni, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ pé àwọn òkú tó wà ní pọ́gátórì lè jáde lọ́jọ́ yẹn sí àwọn tó ṣe wọ́n níbi nígbà tí wọ́n wà láàyè. Wọ́n lè yọ sí wọn bí iwin, àǹjọ̀nnú, àjẹ́, ọ̀pọ̀lọ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.”

    •  Qingming (Ch’ing Ming) àti Hungry Ghost. Wọ́n máa ń ṣe ayẹyẹ méjèèjì yìí láti júbà àwọn baba ńlá. Ìwé Celebrating Life Customs Around the World​—From Baby Showers to Funerals sọ pé nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ayẹyẹ Ch’ing Ming, “wọ́n máa ń fi iná sun oúnjẹ, wáìnì àti owó bébà kí ebi má bàa pa àwọn òkú, kí òùngbẹ má bàa gbẹ wọ́n, kí wọ́n sì lè rówó ná.” Ìwé náà tún sọ pé “ní oṣù tí wọ́n bá ń ṣe ayẹyẹ Hungry Ghost, pàápàá ní alẹ́ òṣùpá àrànmọ́jú, àwọn tó ń ṣayẹyẹ yìí gbà pé àwọn òkú àtàwọn alààyè máa ń ní àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ kan lálẹ́ ọjọ́ yìí ju alẹ́ ọjọ́ míì lọ, torí náà, wọ́n gbà pé ó ṣe pàtàkì káwọn tu àwọn òkú lójú, káwọn sì júbà àwọn baba ńlá wọn.”

    •  Chuseok. Ìwé The Korean Tradition of Religion, Society, and Ethics sọ pé lákòókò tí wọ́n bá ń ṣe ayẹyẹ yìí “wọ́n máa ń fi oúnjẹ àti wáìnì rúbọ sí ọkàn àwọn òkú.” Ẹbọ tí wọ́n ń rú yìí fi hàn pé “wọ́n gbà gbọ́ pé ọkàn máa ń wà láàyè lẹ́yìn tí ara bá kú.”

     Àwọn ayẹyẹ tó jẹ́ mọ́ iṣẹ́ òkùnkùn. Bíbélì sọ pé: “Ẹnì kankan . . . kò gbọ́dọ̀ woṣẹ́, kò gbọ́dọ̀ pidán, kò gbọ́dọ̀ wá àmì ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀, kò gbọ́dọ̀ di oṣó, kò gbọ́dọ̀ fi èèdì di àwọn ẹlòmíì, kò gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò tàbí woṣẹ́woṣẹ́, kò sì gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ òkú . . . Jèhófà kórìíra ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.” (Diutarónómì 18:​10-12) Torí pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í sún mọ́ ohunkóhun tó ní in ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ òkùnkùn títí kan wíwo ìràwọ̀ (tó jẹ́ ara iṣẹ́ awò)​—a kì í ṣe ayẹyẹ Halloween àtàwọn ayẹyẹ tó tẹ̀ lé e yìí:

    •  Sinhala àti Ọdún Tuntun Tamil. Ìwé gbédègbéyọ̀ kan sọ pé, “Àwọn ètùtù kan wà tí wọ́n máa ń ṣe nínú ayẹyẹ yìí,. . . ó sì máa ń jẹ́ lákòókò kan pàtó tí àwọn awòràwọ̀ gbà pé á jẹ́ káwọn èèyàn ṣoríire.”​—Encyclopedia of Sri Lanka.

    •  Songkran. Ilẹ̀ Éṣíà ni ayẹyẹ yìí ti wọ́pọ̀, “inú ọ̀rọ̀ Sanskrit ni wọ́n sì ti mú orúkọ náà . . . èyí tó túmọ̀ sí ‘ìṣípòpadà tàbí ‘ìyípadà’ láti fi ṣayẹyẹ bí oòrùn ṣe ṣípò pa dà kúrò níbi tó wà bọ́ sínú àgbájọ ìràwọ̀ Aries.”​—Food, Feasts, and Faith​​—An Encyclopedia of Food Culture in World Religions.

     Àwọn ayẹyẹ tó jẹ mọ́ ìjọsìn nínú òfin Mósè àmọ́ tí ikú Jésù fòpin sí. Bíbélì sọ pé: “Kristi ni òpin òfin.” (Róòmù 10:4) Àwa Kristẹni mọyì àwọn ìlànà tó wà nínú òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípasẹ̀ Mósè, kódà wọ́n ń ṣe wá láǹfààní. Àmọ́, a kì í ṣe àwọn ayẹyẹ tí òfin náà pa láṣẹ, ní pàtàkì èyí tó sọ nípa wíwá Mèsáyà, táwa Kristẹni sì gbà pé ó ti wá ó ti lọ. Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí? Ó ní: “Àwọn nǹkan yẹn jẹ́ òjìji àwọn ohun tó ń bọ̀, àmọ́ Kristi ni ohun gidi náà.” (Kólósè 2:17) Ó ṣe kedere pé àwọn ayẹyẹ yẹn ti parí iṣẹ́ wọn. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún ti ṣe àmúlùmálà wọn pẹ̀lú àwọn àṣà tí kò bá Bíbélì mu. Pẹ̀lú àwọn àlàyé yìí lọ́kàn, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe àwọn ayẹyẹ tó tẹ̀ lé e yìí:

    •  Hanukkah. Ayẹyẹ yìí ni wọ́n fi máa ń rántí bí wọ́n ṣe ya Tẹ́ńpìlì àwọn Júù tó wà ní Jerúsálẹ́mù sí mímọ́ lẹ́ẹ̀kejì. Bó ti wù kó rí, Bíbélì sọ pé Jésù ti di Àlùfáà Àgbà “àgọ́ tó tóbi jù, tó sì jẹ́ pípé jù, tí wọn ò fi ọwọ́ ṣe, ìyẹn tí kì í ṣe ti ẹ̀dá yìí.” (Hébérù 9:11) Ní tàwa Kristẹni, Tẹ́ńpìlì tẹ̀mí yìí ti rọ́pò tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù.

    •  Rosh Hashanah. Èyí jẹ́ ọjọ́ àkọ́kọ́ nínú ọdún àwọn Júù. Nígbà àtijọ́, tí wọ́n bá ń ṣe ayẹyẹ yìí wọ́n máa ń rú àwọn ẹbọ kan lákànṣe sí Ọlọ́run. (Nọ́ńbà 29:​1-6) Àmọ́, Jésù Kristi tó jẹ́ Mèsáyà ti “mú kí ẹbọ àti ọrẹ dópin,” ó tipa bẹ́ẹ̀ sọ wọ́n di ohun tí kò wúlò mọ́ lójú Ọlọ́run.​—Dáníẹ́lì 9:​26, 27.

  •   Ṣé ayẹyẹ náà máa mú kéèyàn ṣe àmúlùmálà ẹ̀sìn?

     Ìlànà Bíbélì: “Kí ló pa onígbàgbọ́ àti aláìgbàgbọ́ pọ̀? Kí ló pa òrìṣà pọ̀ mọ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run?”​—2 Kọ́ríńtì 6:​15-17.

     Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti wà ní àlááfíà pẹ̀lú àwọn aládùúgbò wa, a kì í kọjá àyè wa, a sì máa ń fọ̀wọ̀ oníkálùkù wọ̀ wọ́n torí a mọ̀ pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n. Síbẹ̀, a kì í lọ́wọ́ nínú ayẹyẹ èyíkéyìí tó ní in ṣe pẹ̀lú àmúlùmálà ẹ̀sìn, bíi tàwọn tó tẹ̀ lé e yìí.

     Àwọn ayẹyẹ tí wọ́n fi ń ṣàyẹ́sí onísìn kan tàbí tó ń mú káwọn ẹlẹ́sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ máa jọ́sìn pa pọ̀. Ìtọ́ni kan wà tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ nígbà tó ń darí wọn lọ sí ilẹ̀ tó ṣèlérí fún wọn. Torí pé ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ làwọn èèyàn ilẹ̀ yẹn ń ṣe, Jèhófà sọ fáwọn èèyàn tiẹ̀ pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ bá àwọn èèyàn náà tàbí ọlọ́run wọn dá májẹ̀mú. . . . Tí ẹ bá lọ sin àwọn ọlọ́run wọn, ó dájú pé yóò di ìdẹkùn fún yín.” (Ẹ́kísódù 23:​32, 33) Fún ìdí yìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe àwọn ayẹyẹ tó tẹ̀ lé e yìí.

    •  Loy Krathong. Ilẹ̀ Thailand ni ayẹyẹ yìí ti wọ́pọ̀, lásìkò ayẹyẹ náà, “àwọn èèyàn máa ń hun ewé pọ̀ láti ṣe abọ́, wọ́n á kó àbẹ́là tàbí tùràrí sínú abọ́ ewé náà, wọ́n á wá gbé e sórí omi. Wọ́n gbà gbọ́ pé èyí máa mú kí orí burúkú ba omi lọ. Ńṣe ni wọ́n ń fi ayẹyẹ náà rántí iṣẹ́ mímọ́ tí Buddha ṣe.”​—Encyclopedia of Buddhism.

    •  Ọjọ́ Ìrònúpìwàdà. Nínú ìwé ìròyìn The National, ti orílẹ̀-èdè Papua New Guinea, òṣìṣẹ́ ìjọba kan sọ pé àwọn tó máa ń para pọ̀ láti ṣe ayẹyẹ yìí “fara mọ́ àwọn kan lára ẹ̀kọ́ àti àṣà àwọn ẹlẹ́sìn Kristi.” Ó tún sọ pé ọjọ́ yìí ni wọ́n á fi máa rán àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè náà létí “àwọn ìlànà Kristẹni tó yẹ kí wọ́n máa tẹ̀ lé.”

    •  Vesak. “Ọjọ́ yìí làwọn onísìn Búdà kà sí ọjọ́ mímọ́ jù lọ. Ọjọ́ yìí ni wọ́n máa ń ṣe ayẹyẹ ìrántí ọjọ́ ìbí Búdà, ọjọ́ tó gba ìlàlóye àti ọjọ́ tó kú tàbí tó wọnú Nirvana.”​—Holidays, Festivals, and Celebrations of the World Dictionary.

      Ayẹyẹ Vesak

     Àwọn ayẹyẹ tó dá lórí ààtò ẹ̀sìn tí kò bá Bíbélì mu. Jésù sọ fún àwọn aṣáájú ẹ̀sìn pé: “Ẹ ti wá sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di èyí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nítorí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yín.” Ó tún jẹ́ kó ṣe kedere sí wọn asán lórí asán ni ìjọsìn wọn torí pé “àṣẹ èèyàn ni ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni.” (Mátíù 15:​6, 9) Ọwọ́ gidi làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi mu ọ̀rọ̀ Jésù yìí, torí ẹ̀ ọ̀pọ̀ ayẹyẹ ìsìn ni a kì í ṣe.

    •  Epiphany (Ọjọ́ àwọn Ọba mẹ́ta, Timkat, tàbí Los Reyes Magos). Ayẹyẹ yìí làwọn tó ń ṣe é fi máa ń rántí ìgbà táwọn awòràwọ̀ lọ kí Jésù tàbí ọjọ́ tí Jésù ṣèrìbọmi. Ìwé kan tiẹ̀ sọ pé, “Níbẹ̀rẹ̀, àwọn abọ̀rìṣà ló máa ń ṣe ayẹyẹ yìí nígbà ìrúwé láti fi júbà òòṣà omi àti òòṣà odò. Àmọ́ nígbà tó yá, ó di àjọ̀dún tàwọn Kristẹni ń ṣe.” (The Christmas Encyclopedia) Inú “àwọn àṣà ìbílẹ̀” náà ni ayẹyẹ Timkat tó fara jọ Epiphany ti wá.​—Encyclopedia of Society and Culture in the Ancient World.

    •  Assumption. Àwọn tó ń ṣe ayẹyẹ yìí gbà pé ńṣe ni Màríà ìyá Jésù lọ sọ́run láì bọ́ ẹran ara sílẹ̀. Ìwé Religion and Society​—Encyclopedia of Fundamentalism sọ pé “Àwọn tó kọ́kọ́ di Kristẹni kò gba ẹ̀kọ́ yìí gbọ́, kò sì sí ẹ̀rí kankan nínú Ìwé Mímọ́ tó ti èrò náà lẹ́yìn.”

    •  Immaculate Conception. Èyí ni wọ́n fi máa ń ṣàjọyọ̀ pé aláìlẹ́ṣẹ̀ ni Màríà nígbà tó lóyún Jésù. Àmọ́, ìwé New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Kò síbì kankan nínú Bíbélì tó sọ pé Màríà jẹ́ aláìlẹ́ṣẹ̀ nígbà tó lóyún . . . Àdábọwọ́ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni.”

    •  Lẹ́ǹtì. Àsìkò yìí làwọn èèyàn máa ń kábàámọ̀ tí wọ́n sì máa ń gbààwẹ̀ torí àṣìṣe wọ́n. Ìwé New Catholic Encyclopedia sọ pé, “ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin” ni wọ́n dá ayẹyẹ yìí sílẹ̀, ìyẹn lóhun tó ju ọgọ́rùn-ún méjì ọdún lọ lẹ́yìn tí wọ́n ti parí kíkọ́ Bíbélì. Ìwé yìí kan náà sọ bí ààtò Lẹ́ǹtì ṣe bẹ̀rẹ̀, ó ní: “Àpérò kan tó wáyé nílùú Benevento lọ́dún 1091 ni wọ́n ti pinnu pé káwọn onígbàgbọ́ máa gba àmì eérú sórí lọ́jọ́ Ash Wednesday, ìgbà yẹn náà ló sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í tàn kálẹ̀.”

    •  Meskel (tàbí, Maskal). Ìwé Encyclopedia of Society and Culture in the Medieval World sọ pé ayẹyẹ àwọn ará Etiópíà yìí ni wọ́n fi ń ṣe àjọ̀dún “bí wọ́n ṣe rí Àgbélébùú Tòótọ́ (ìyẹn àgbélébùú tí wọ́n kan Jésù mọ́ gan-an). Nígbà ayẹyẹ yìí, wọ́n á dáná, wọ́n á wá máa jó yípo iná náà.” Àmọ́ o, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í lo àgbélébùú nínú ìjọsìn wa.

  •   Ṣé ayẹyẹ tó ń gbé ẹnì kan, ètò kan tàbí àsíá orílẹ̀-èdè kan lárugẹ ni?

     Ìlànà Bíbélì: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ègún ni fún ọkùnrin tó gbẹ́kẹ̀ lé èèyàn lásánlàsàn, tó gbára lé agbára èèyàn, tí ọkàn rẹ̀ sì pa dà lẹ́yìn Jèhófà.”​—Jeremáyà 17:5.

     Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fi hàn pé a mọyì àwọn èèyàn, a sì tún máa ń gbàdúrà fún wọn, a kì í ṣe àwọn ayẹyẹ tó tẹ̀ lé e yìí:

     Ayẹyẹ tí wọ́n fi ń bọlá fún alákòóso tàbí olókìkí èèyàn. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Fún àǹfààní ara yín, ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé èèyàn lásán mọ́, ẹni tí kò yàtọ̀ sí èémí ihò imú rẹ̀. Kí nìdí tí ẹ fi máa kà á sí?” (Àìsáyà 2:22) Torí bẹ́ẹ̀, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọba tàbí ayaba èyíkéyìí.

     Ayẹyẹ àsíá orílẹ̀-èdè. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ayẹyẹ Flag Day, ìyẹn ọjọ́ Àsíá. Kí nìdí? Torí ohun tí Bíbélì sọ ni, pé: “Ẹ máa yẹra fún àwọn òrìṣà.” (1 Jòhánù 5:21) Àwọn kan ò gbà pé ère ni àsíá àti pé ohun tí wọ́n ń lò fún ìjọsìn ni. Àmọ́, òpìtàn kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ CarltonJ. Huntley Hayes sọ pé: “Àsíá jẹ́ àmì ìgbàgbọ́ tó ṣe pàtàkì àti ohun ìjọsìn kan ṣoṣo tí gbogbo àwọn tó ní ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ń júbà.”

     Ayẹyẹ tó ń gbé àwọn tí wọ́n kà sí ẹni mímọ́ lárugẹ. Kí ni àpọ́sítélì Pétérù ṣe nígbà tí ọkùnrin kan tó bẹ̀rù Ọlọ́run tẹrí ba fún un? Bíbélì sọ pé: “Pétérù gbé e dìde, ó sọ pé: ‘Dìde; èèyàn lèmi náà.’” (Ìṣe 10:​25, 26) Níwọ̀n bí Pétérù tàbí àpọ́sítélì èyíkéyìí ò ti gbà kí ẹnikẹ́ni fún wọn láfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ tàbí júbà wọn, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í lọ́wọ́ nínú ayẹyẹ tí wọ́n fí ń bọlá fáwọn tí wọ́n kà sí ẹni mímọ́. Àpẹẹrẹ àwọn ayẹyẹ ló tẹ̀ lé e yìí:

    •  All Saints’ Day. “Wọ́n máa ń se àsè láti fi bọlá fún gbogbo ẹni mímọ́ . . . A ò mọ àwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ayẹyẹ yìí.”​—New Catholic Encyclopedia.

    •  Our Lady of Guadalupe. Ayẹyẹ yìí ni wọ́n fi máa ń júbà Màríà ìyà Jésù tí ọ̀pọ̀ gbà pé ó jẹ́ “ẹni mímọ́ jù lọ ní Mẹ́síkò.” Wọ́n sọ pé òun ló fara han àgbẹ̀ kan lọ́nà ìyanu lọ́dún 1531.​—The Greenwood Encyclopedia of Latino Literature.

      Ayẹyẹ Our Lady of Guadalupe

    •  Name Day. Ìwé Celebrating Life Customs Around the World​—From Baby Showers to Funerals sọ pé ‘Láwọn ilẹ̀ kan, ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ọdún ló ní orúkọ ẹni mímọ́ kan pàtó. Torí náà, tí wọ́n bá ṣèrìbọmi tàbí ìyàsímímọ́ ẹlẹ́ẹ̀kejì fún ọmọ kan, wọ́n á sọ ọmọ náà lórúkọ ẹni mímọ́ ọjọ́ yẹn. Nípa bẹ́ẹ̀, ayẹyẹ àyájọ́ ọjọ́ ẹni mímọ́ yẹn ni wọ́n ń pè ní Name Day.’ Ìwé Celebrating Life Customs wá fi kún un pé: “Onírúurú ààtò ìsìn tó rinlẹ̀ ni wọ́n máa ń ṣe lọ́jọ́ yìí.”

     Ayẹyẹ òṣèlú tàbí ìpolongo ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Bíbélì sọ pé “Ó sàn láti fi Jèhófà ṣe ibi ààbò ju láti gbẹ́kẹ̀ lé èèyàn.” (Sáàmù 118:​8, 9) Kò lè ṣe kedere sáwọn èèyàn pé Jèhófà la gbẹ́kẹ̀ lé láti yanjú ìṣòro aráyé dípò èèyàn, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í lọ́wọ́ sí àwọn ayẹyẹ tó ní in ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Àpẹẹrẹ kan ni Youth Day, ìyẹn ayẹyẹ Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́ tàbí Women’s Day, ìyẹn ayẹyẹ Ọjọ́ Àwọn Obìnrin. Ìdí yìí kan náà ni kì í jẹ́ ká lọ́wọ́ sí Emancipation Day, ìyẹn ayẹyẹ àyájọ́ ọjọ́ tí ìjọba fòpin sí òwò ẹrú ṣíṣe àtàwọn ayẹyẹ míì tó jọ ọ́. Dípò akitiyan àwọn èèyàn, Ìjọba Ọlọ́run nìkan la gbà pé ó máa yanjú ìṣòro kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti ìwà ìrẹ́nijẹ.​—Róòmù 2:11; 8:21.

  •   Ṣé ayẹyẹ náà gbé orílẹ̀-èdè kan tàbí ẹ̀yà kan ga ju òmíì lọ?

     Ìlànà Bíbélì: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, àmọ́ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ ni ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.”​—Ìṣe 10:​34, 35.

     Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọyì ìlú wa, a kì í ṣe dá sí ayẹyẹ tó bá ti ń gbé ẹ̀yà kan tàbí orílẹ̀-èdè kan lárugẹ, bí àwọn tó tẹ̀ lé e yìí.

     Àwọn ayẹyẹ tí wọ́n fi ń bọlá fún àwọn ológun. Dípò tí Jésù á fi rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n jagun, ńṣe ló sọ fún wọ́n pé: “Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún àwọn tó ṣenúnibíni sí yín.” (Mátíù 5:44) Nítorí náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í lọ́wọ́ nínú ayẹyẹ èyíkéyìí tí wọ́n fi ń bọlá fún àwọn ológun, títí kan àwọn tá a mẹ́nu kàn nísàlẹ̀ yìí:

    •  Anzac Day. Ìwé Historical Dictionary of Australia sọ pé: “Anzac ni ìkékúrú Australian and New Zealand Army Corps,” ìyẹn àwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè Ọsirélíà àti New Zealand. Ó wá fi kún un pé, “Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ tí wọ́n pè ní Anzac Day tí wọ́n fi ń rántí àwọn tó kú sójú ogun.”

    •  Veterans Day (Remembrance Day, Remembrance Sunday, or Memorial Day). Wọ́n máa ń fi àwọn ayẹyẹ yìí bọlá fún àwọn akínkanjú ọmọ ogun àtàwọn tó kú sójú ogun tí orílẹ̀-èdè náà jà.”​—Encyclopædia Britannica.

     Ayẹyẹ ìtàn orílẹ̀-èdè tàbí ayẹyẹ òmìnira. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, bí èmi ò ṣe jẹ́ apá kan ayé.” (Jòhánù 17:16) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń dùn láti mọ̀ nípa ìtàn orílẹ̀-èdè kan, a kì í lọ́wọ́ sáwọn ayẹyẹ tó tẹ̀ lé e yìí:

    •  Australia Day. Ìwé Worldmark Encyclopedia of Cultures and Daily Life sọ pé wọ́n máa ń fi ayẹyẹ yìí rántí “ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan lọ́dún 1788, nígbà tí àwọn ọmọ ogun Gẹ̀ẹ́sì ta àsíá wọn sókè tí wọ́n sì kéde pé Ọsirélíà ti bọ́ sábẹ́ àkóso ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.”

    •  Guy Fawkes Day. Ọjọ́ yìí “ni wọ́n máa ń rántí ohun kan tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1605, tí Guy Fawkes àtàwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ tí wọ́n jọ jẹ́ onísìn Kátólíìkì gbìmọ̀ láti pa Ọba James Àkọ́kọ́ àtàwọn tó jọ ń ṣàkóso nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àmọ́ tí wọn ò ṣàṣeyọrí.”​—A Dictionary of English Folklore.

    •  Ọjọ́ Òmìnira. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, “ọjọ́ yìí làwọn èèyàn máa ń ṣayẹyẹ bí orílẹ̀-èdè wọn ṣe gba òmìnira lọ́wọ́ orílẹ̀-èdè míì.”​—Merriam-Webster’s Unabridged Dictionary.

  •   Ṣé ayẹyẹ tó ń gbé ìwà àìníjàánu tàbí ìṣekúṣe lárugẹ ni?

     Ìlànà Bíbélì: “Torí àkókò tó ti kọjá tí ẹ fi ṣe ìfẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè ti tó yín, nígbà tí ẹ̀ ń hu ìwà àìnítìjú, tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, tí ẹ̀ ń mu ọtí àmujù, ṣe àríyá aláriwo, ṣe ìdíje ọtí mímu àti àwọn ìbọ̀rìṣà tó jẹ́ ohun ìríra.”​—1 Pétérù 4:3.

     Ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà yìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe àwọn ayẹyẹ táwọn èèyàn ti máa ń mutí yó, bẹ́ẹ̀ la ò kì í lọ síbi àríyá aláriwo. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kóra jọ láti gbádùn pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa, a sì lè mu ọtí, ìyẹn ní ìwọ̀nba tá a bá tiẹ̀ mu rárá. A máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò tó sọ pé: “Bóyá ẹ̀ ń jẹ tàbí ẹ̀ ń mu tàbí ẹ̀ ń ṣe ohunkóhun míì, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.”​—1 Kọ́ríńtì 10:31.

     Nípa bẹ́ẹ̀, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í lọ́wọ́ sí àwọn àjọ̀dún tàbí ayẹyẹ tó ń gbé ìwà tí kò bójú mu tàbí tí inú Ọlọ́run kò dùn sí lárugẹ. Ọ̀kan lára ayẹyẹ bẹ́ẹ̀ ni Purim táwọn Júù máa ń ṣe. Lóòótọ́, ó pẹ́ táwọn Júù ti máa ń ṣe ayẹyẹ yìí láti rántí bí wọ́n ṣe rí ìdáǹdè ní Ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àmọ́ ní báyìí nǹkan míì ti wọ̀ ọ́. Ìwé Essential Judaism sọ pé “ká kúkú sọ pé ayẹyẹ Mardi Gras tàbí Carnival làwọn Júù ń ṣe bó tiẹ̀ jẹ́ pé Purim ni wọ́n sọ pé àwọn ń ṣe.” Ìwé yìí kan náà sọ nípa àwọn tó nífẹ̀ẹ́ àríyá aláriwo pé “onírúurú aṣọ ni wọ́n máa ń wọ̀, bíi kí ọkùnrin wọṣọ obìnrin, wọ́n á máa pariwo, wọ́n á mutí yó, wọ́n á sì máa hùwà ẹhànnà.”

 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe àwọn ayẹyẹ kan, ǹjẹ́ a ṣì nífẹ̀ẹ́ ìdílé wa?

 Bẹ́ẹ̀ ni. Bíbélì sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn tó wà nínú ìdílé wa ká sì bọ̀wọ̀ fún wọn bí ìgbàgbọ́ wọn bá tiẹ̀ yàtọ̀ sí tiwa. (1 Pétérù 3:​1, 2, 7) Òótọ́ ni pé, tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan kò bá ṣe àwọn ayẹyẹ kan mọ́, inú lè bí àwọn kan lára mọ̀lẹ́bí rẹ̀, wọ́n tiẹ̀ lè ronú pé ṣe ló pa àwọn tì. Nítorí náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fi àwọn mọ̀lẹ́bí wa lọ́kàn balẹ̀, a sì máa ń jẹ́ kó dá wọn lójú pé àwọn nífẹ̀ẹ́ wọn. Bákan náà, á máa ń fọgbọ́n ṣàlàyé ìdí tá ò fi lọ́wọ́ sáwọn ayẹyẹ kan mọ́, a sì máa ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn láwọn àkókò míì.

 Ṣé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sọ fáwọn míì pé wọn ò gbọdọ̀ ṣe àwọn ayẹyẹ kan?

 Rárá, a kì í ṣe bẹ́ẹ̀. A gbà pé ẹni kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu fúnra ẹ̀ bóyá òun á lọ́wọ́ nínú ayẹyẹ kan tàbí òun ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. (Jóṣúà 24:15) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń “bọlá fún onírúurú èèyàn” láìkà ẹ̀sìn yòówù kí wọ́n máa ṣe.​—1 Pétérù 2:17.

a Kì í ṣe gbogbo ayẹyẹ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe la sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ́ yìí, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe gbogbo ìlànà Bíbélì tó kan ọ̀rọ̀ ayẹyẹ la mẹ́nu bà.

b Ìwé Mithra, Mithraism, Christmas Day & Yalda, láti ọwọ́ K. E. Eduljee, ojú ìwé 31 sí 33.