Sáàmù 34:1-22

  • Jèhófà ń gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀

    • “Ẹ jẹ́ ká jọ gbé orúkọ rẹ̀ ga” (3)

    • Áńgẹ́lì Jèhófà ń dáàbò boni (7)

    • “Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé ẹni rere ni Jèhófà” (8)

    • ‘Kò sí ìkankan nínú egungun rẹ̀ tí ó ṣẹ́’ (20)

Ti Dáfídì, nígbà tó ń ṣe bí ayírí+ níwájú Ábímélékì, tí Ábímélékì fi lé e jáde, tí ó sì lọ. א [Áléfì] 34  Èmi yóò máa yin Jèhófà ní gbogbo ìgbà;Ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi nígbà gbogbo. ב [Bétì]   Èmi* yóò máa fi Jèhófà yangàn;+Àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ yóò gbọ́, wọn yóò sì máa yọ̀. ג [Gímélì]   Ẹ bá mi gbé Jèhófà ga;+Ẹ jẹ́ ká jọ gbé orúkọ rẹ̀ ga. ד [Dálétì]   Mo wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì dá mi lóhùn.+ Ó gbà mí sílẹ̀ nínú gbogbo ohun tó ń bà mí lẹ́rù.+ ה [Híì]   Ojú àwọn tó gbára lé e ń dán;Kò sí ohun tó lè kó ìtìjú bá wọn. ז [Sáyìn]   Aláìní yìí pe Jèhófà, ó sì gbọ́. Ó gbà á nínú gbogbo wàhálà rẹ̀.+ ח [Hétì]   Áńgẹ́lì Jèhófà pàgọ́ yí àwọn tó bẹ̀rù Rẹ̀ ká,+Ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.+ ט [Tétì]   Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé ẹni rere ni Jèhófà,+Aláyọ̀ ni ọkùnrin tí ó fi í ṣe ibi ààbò. י [Yódì]   Ẹ bẹ̀rù Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ẹni mímọ́ rẹ̀,Nítorí àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ kò ní ṣaláìní.+ כ [Káfì] 10  Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ebi máa ń pa àwọn ọmọ kìnnìún* tó lágbára,Àmọ́ ní ti àwọn tó ń wá Jèhófà, wọn kò ní ṣaláìní ohun rere.+ ל [Lámédì] 11  Ẹ wá, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí mi;Màá kọ́ yín ní ìbẹ̀rù Jèhófà.+ מ [Mémì] 12  Ta ló fẹ́ máa gbádùn ìgbésí ayé rẹ̀ nínú yínTí ó sì fẹ́ ẹ̀mí gígùn, kó lè máa rí ohun rere?+ נ [Núnì] 13  Nígbà náà, ṣọ́ ahọ́n rẹ, má ṣe sọ ohun búburú,+Má sì fi ètè rẹ ṣẹ̀tàn.+ ס [Sámékì] 14  Jáwọ́ nínú ohun búburú, kí o sì máa ṣe rere;+Máa wá àlàáfíà, kí o sì máa lépa rẹ̀.+ ע [Áyìn] 15  Ojú Jèhófà wà lára àwọn olódodo,+Etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́.+ פ [Péè] 16  Àmọ́, Jèhófà kọjú ìjà sí àwọn tó ń ṣe ohun búburú,Láti pa wọ́n rẹ́ kúrò láyé kí wọ́n sì di ẹni ìgbàgbé.+ צ [Sádì] 17  Wọ́n ké jáde, Jèhófà sì gbọ́;+Ó gbà wọ́n sílẹ̀ nínú gbogbo wàhálà wọn.+ ק [Kófì] 18  Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn;+Ó ń gba àwọn tí àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn* là.+ ר [Réṣì] 19  Ìṣòro* olódodo máa ń pọ̀,+Àmọ́ Jèhófà ń gbà á sílẹ̀ nínú gbogbo rẹ̀.+ ש [Ṣínì] 20  Ó ń dáàbò bo gbogbo egungun rẹ̀;Kò sí ìkankan nínú wọn tí a ṣẹ́.+ ת [Tọ́ọ̀] 21  Àjálù ló máa pa ẹni burúkú;A ó sì dẹ́bi fún àwọn tó kórìíra olódodo. 22  Jèhófà ń ra ẹ̀mí* àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pa dà;Kò sí ìkankan lára àwọn tó fi í ṣe ibi ààbò tí a ó dá lẹ́bi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Ọkàn mi.”
Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
Tàbí “tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá.”
Tàbí “Àjálù.”
Tàbí “ọkàn.”