Sáàmù 91:1-16
91 Ẹni tó bá ń gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ+Yóò máa gbé lábẹ́ òjìji Olódùmarè.+
2 Màá sọ fún Jèhófà pé: “Ìwọ ni ibi ààbò mi àti odi ààbò mi,+Ọlọ́run mi tí mo gbẹ́kẹ̀ lé.”+
3 Nítorí yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ pańpẹ́ pẹyẹpẹyẹ,Lọ́wọ́ àjàkálẹ̀ àrùn tó ń pani run.
4 Yóò fi àwọn ìyẹ́ tó fi ń fò bò ọ́,*Wàá sì fi abẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀ ṣe ibi ààbò.+
Òtítọ́ rẹ̀+ yóò jẹ́ apata+ ńlá àti odi* ààbò.
5 O ò ní bẹ̀rù àwọn ohun tó ń kó jìnnìjìnnì báni ní òru+Tàbí ọfà tó ń fò ní ọ̀sán+
6 Tàbí àjàkálẹ̀ àrùn tó ń yọ́ kẹ́lẹ́ nínú òkùnkùnTàbí ìparun tó ń ṣọṣẹ́ ní ọ̀sán gangan.
7 Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹÀti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,
Àmọ́ kò ní sún mọ́ ọ.+
8 Ojú rẹ nìkan ni wàá fi rí iBí o ṣe ń wo ìyà* àwọn ẹni burúkú.
9 Nítorí o sọ pé: “Jèhófà ni ibi ààbò mi,”O ti fi Ẹni Gíga Jù Lọ ṣe ibùgbé* rẹ;+
10 Àjálù kankan kò ní bá ọ,+Àjàkálẹ̀ àrùn kankan kò sì ní sún mọ́ àgọ́ rẹ.
11 Torí ó máa pàṣẹ fún àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ nítorí rẹ,+Láti máa ṣọ́ ọ ní gbogbo ọ̀nà rẹ.+
12 Wọ́n á fi ọwọ́ wọn gbé ọ,+Kí o má bàa fi ẹsẹ̀ rẹ gbá òkúta.+
13 Wàá rìn kọjá lórí ọmọ kìnnìún àti ṣèbé;Wàá tẹ kìnnìún onígọ̀gọ̀* àti ejò ńlá mọ́lẹ̀.+
14 Ọlọ́run sọ pé: “Nítorí ó nífẹ̀ẹ́ mi,* màá gbà á sílẹ̀.+
Màá dáàbò bò ó torí pé ó mọ* orúkọ mi.+
15 Yóò ké pè mí, màá sì dá a lóhùn.+
Màá dúró tì í nígbà wàhálà.+
Màá gbà á sílẹ̀, màá sì ṣe é lógo.
16 Màá fi ẹ̀mí gígùn tẹ́ ẹ lọ́rùn,+Màá sì jẹ́ kó rí àwọn iṣẹ́ ìgbàlà mi.”*+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “bo ọ̀nà àbáwọlé rẹ.”
^ Tàbí “ògiri.”
^ Ní Héb., “ẹ̀san.”
^ Tàbí kó jẹ́, “ibi ààbò; odi ààbò.”
^ Tàbí “kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe.”
^ Ní Héb., “ó ti dara pọ̀ mọ́ mi.”
^ Tàbí “bọlá fún.”
^ Tàbí “rí ìgbàlà láti ọ̀dọ̀ mi.”