Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

AYÉ DOJÚ RÚ

4 | Gbà Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa

4 | Gbà Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa

ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ

Àníyàn nípa bí nǹkan ṣe ń dojú rú láyé yìí lè mú kí nǹkan tojú sú àwọn èèyàn, kó sì ṣàkóbá fún ìlera wọn. Kódà, ó lè mú káwọn kan gbà pé kò sọ́nà àbáyọ mọ́. Kí làwọn èèyàn sábà máa ń ṣe tí nǹkan bá dojú rú?

  • Àwọn kan ò ní fẹ́ ronú nípa ọjọ́ iwájú mọ́.

  • Àwọn míì máa ń fi ọtí àbí oògùn olóró pàrònú rẹ́.

  • Àwọn míì gbà pé ikú yá ju ẹ̀sín, torí náà wọ́n á gbìyànjú láti para wọn.

Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀

  • Nǹkan lè yí pa dà nígbàkigbà kó o sì rí ojútùú sí díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tó ò ń kojú báyìí.

  • Tí ìṣòro náà ò bá tiẹ̀ yanjú, àwọn nǹkan kan ṣì wà tó o lè ṣe láti máa fara dà á.

  • Bíbélì sọ fún wa pé Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ìṣòro tó wà láyé yìí.

Ohun Tó O Lè Ṣe Ní Báyìí

Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, torí ọ̀la máa ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Wàhálà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un.”​—Mátíù 6:34.

Má ṣe jẹ́ kí àníyàn nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la dẹ́rù bà ẹ́, débi tó ò fi ní lè bójú tó àwọn ohun tó yẹ kó o ṣe lónìí.

Tó o bá ń ṣàníyàn jù nípa àwọn nǹkan burúkú tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀, ńṣe ni wàá máa gbọ́kàn sókè, ìyẹn á sì mú kí nǹkan túbọ̀ tojú sú ẹ.

Bíbélì Jẹ́ Ká Mọ̀ Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa

Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, onísáàmù kan gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi àti ìmọ́lẹ̀ fún ọ̀nà mi.” (Sáàmù 119:105) Jẹ́ ká wo àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé òótọ́ lohun tí onísáàmù yẹn sọ.

Tẹ́nì kan bá ń rìn nínú òkùnkùn lálẹ́, ọkàn ẹ̀ máa balẹ̀ tó bá tan tọ́ọ̀ṣì torí ìyẹn á jẹ́ kó mọ ibi tó yẹ kó gbà. Bákan náà, ṣe ni Bíbélì dà bí ìmọ́lẹ̀ torí ó láwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó máa tọ́ wa sọ́nà, táá sì ràn wá lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó tọ́.

Tẹ́nì kan bá tanná nínú òkùnkùn, ìyẹn lè jẹ́ kó rí ohun tó wà lọ́nà jíjìn. Bákan náà, Bíbélì lè jẹ́ ká mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la.