Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

AYÉ DOJÚ RÚ

3 | Jẹ́ Kí Àjọṣe Ìwọ àti Tẹbítọ̀rẹ́ Dáa Sí I

3 | Jẹ́ Kí Àjọṣe Ìwọ àti Tẹbítọ̀rẹ́ Dáa Sí I

ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ

Torí pé nǹkan túbọ̀ ń burú sí i láyé yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ti jẹ́ kíyẹn ṣàkóbá fún àjọṣe àwọn pẹ̀lú ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn.

  • Àwọn èèyàn kan máa ń fẹ́ dá wà.

  • Àwọn tọkọtaya kan ò nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú, wọ́n sì ń hùwà àìdáa síra wọn.

  • Ọ̀pọ̀ àwọn òbí ò rí tàwọn ọmọ wọn rò, wọn ò sì kíyè sí bí nǹkan ṣe rí lára wọn.

Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀

  • Tó o bá ní ọ̀rẹ́ tó dúró tì ẹ́ nígbà ìṣòro, inú ẹ á dùn, ara ẹ á sì yá gágá.

  • Ìgbàkigbà ni nǹkan lè yí pa dà nínú ìdílé torí bí nǹkan ṣe ń nira sí i láyé yìí.

  • Àwọn ìròyìn burúkú tí wọ́n ń gbé jáde lójoojúmọ́ lè dẹ́rù ba àwọn ọmọ ẹ, ìyẹn sì lè má jẹ́ kọ́kàn wọn balẹ̀.

Ohun Tó O Lè Ṣe Ní Báyìí

Bíbélì sọ pé: “Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.”​—Òwe 17:17.

Àwọn ọ̀rẹ́ ẹ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́, wọ́n sì lè fún ẹ ní ìmọ̀ràn táá ṣe ẹ́ láǹfààní. Tó o bá ń rántí pé ẹnì kan wà tó nífẹ̀ẹ́ ẹ, tí ò sì fọ̀rọ̀ ẹ ṣeré, ìyẹn á fún ẹ lókun kó o lè máa fara da ìṣòro èyíkéyìí tó o bá kojú.