Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ÀWỌN ÀṢÀ TÓ LÈ ṢE Ẹ́ LÁǸFÀÀNÍ

3 Má Ṣe Jẹ́ Kó Sú Ẹ

3 Má Ṣe Jẹ́ Kó Sú Ẹ

Ọ̀pọ̀ gbà gbọ́ pé ó máa ń gbà tó ọjọ́ mọ́kànlélógún [21] kí ìwà kan tó lè mọ́ọ̀yàn lára. Àmọ́ ká sòótọ́, ìwádìí fi hàn pé àwọn míì kì í pẹ́ tó bẹ́ẹ̀, àwọn míì sì máa ń pẹ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ kí nǹkan tó mọ́ wọn lára. Ṣé ó wá yẹ kí èyí mú ọ rẹ̀wẹ̀sì?

Ronú nípa àpẹẹrẹ yìí ná: Ká sọ pé ó wù ẹ́ láti máa ṣe eré ìmárale nígbà mẹ́ta lọ́sẹ̀.

  • Lọ́sẹ̀ àkọ́kọ́, ó ṣe dáadáa.

  • Lọ́sẹ̀ kejì, o pa ọjọ́ kan jẹ.

  • Lọ́sẹ̀ kẹta, o tún ṣe dáadáa.

  • Lọ́sẹ̀ kẹrin, ekukáká ló fi ṣe é lọ́jọ́ kan.

  • Lọ́sẹ̀ karùn-ún, o tún ṣe dáadáa, látìgbà yẹn lọ o kò pa ọjọ́ kankan jẹ mọ́.

Ó gba ọ̀sẹ̀ márùn-ún kí àṣà tuntun náà tó mọ́ ẹ lára. Ó lè jọ pé ó pẹ́ gan-an kó tó mọ́ ẹ lára, àmọ́ inú rẹ á dùn pé ọwọ́ rẹ ti tẹ ohun tó o fẹ́.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje pàápàá, yóò sì dìde dájúdájú.”Òwe 24:16.

Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká má ṣe jẹ́ kó sú wa. Kì í ṣe iye ìgbà tá a ṣubú ló ṣe pàtàkì jù, bí kò ṣe iye ìgbà tá a pa dà dìde.

Kì í ṣe iye ìgbà tá a ṣubú ló ṣe pàtàkì jù, bí kò ṣe iye ìgbà tá a pa dà dìde

OHUN TÓ O LÈ ṢE

  • Má ṣe parí èrò sí pé o ti di aláṣetì torí pé ọwọ́ rẹ kò tètè tẹ ohun tó o fẹ́. Wàá máa rí ìfàsẹ́yìn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan bó o ṣe ń sapá láti lé àfojúsùn rẹ bá.

  • Ìgbà tí nǹkan lọ bó o ṣe fẹ́ ni kó o máa rò. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé ńṣe lo fẹ́ mú kí ọ̀nà tó ò ń gbà bá àwọn ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ dára sí i, bí ara rẹ pé: ‘Ìgbà wo ló ṣe mí bíi kí n jágbe mọ́ àwọn ọmọ mi, àmọ́ tí mi ò ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ni mo ṣe dípò ìyẹn? Báwo ni mo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà míì?’ Irú àwọn ìbéèrè báyìí máa jẹ́ kó o lè ronú lórí àwọn àṣeyọrí rẹ dípò àwọn ìfàsẹ́yìn tó o ní.

Ṣé o fẹ́ mọ àwọn ọ̀nà míì tí Bíbélì lè gbà ràn ẹ́ lọ́wọ́, bóyá láti borí àníyàn, bí ìdílé rẹ ṣe lè láyọ̀, àti bó o ṣe lè ní ayọ̀ tó jinlẹ̀? Bá ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀ tàbí kó o lọ sórí ìkànnì wa, ìyẹn jw.org.