Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Àwọn Àṣà Tó Lè Ṣe Ẹ́ Láǹfààní

Àwọn Àṣà Tó Lè Ṣe Ẹ́ Láǹfààní
  • AUSTIN ṣì ń sùn nígbà tí aago rẹ̀ dún. Àmọ́, ó dìde kánmọ́ lórí bẹ́ẹ̀dì, ó wọṣọ tó fi ń ṣeré ìmárale tó ti kó sílẹ̀ láti alẹ́ àná, ó sì jáde lọ sáré, bó ti máa ń ṣe lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́sẹ̀ láti bí ọdún kan sẹ́yìn.

  • Laurie ṣẹ̀ṣẹ̀ bá ọkọ rẹ̀ jà tán ni. Ló bá fi ìbínú lọ sílé ìdáná, ó gbé odindi ṣokoléètì kan, ó sì jẹ gbogbo rẹ̀ tán, bó ṣe máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà tínú bá ti bí i.

Kí ni Austin àti Laurie fi jọra? Yálà wọ́n mọ̀ tàbí wọn ò mọ̀, àwọn méjèèjì ló ní àṣà kan tó ti mọ́ wọn lára.

Ìwọ ńkọ́? Ṣé àwọn nǹkan dáadáa kan wà tó wù ẹ́ láti máa ṣe? Bíi ṣíṣe eré ìmárale déédéé, kó o túbọ̀ máa rí oorun sùn, tàbí kó o túbọ̀ máa ráyè fáwọn tó o fẹ́ràn.

Lọ́wọ́ kejì, ó lè wù ẹ́ láti jáwọ́ nínú àṣà tí kò tọ́, irú bíi mímu sìgá, jíjẹ́ àwọn oúnjẹ pàrùpárù tàbí lílo àkókò tó pọ̀ jù lórí fóònù.

Ká sòótọ́, ó lè má rọrùn láti jáwọ́ nínú àwọn àṣà tí kò dáa. Àwọn kan tiẹ̀ máa ń sọ pé ohun tí kò dáa ló máa ń rọrùn láti ṣe, wẹ́rẹ́ ló máa ń mọ́ọ̀yàn lára, àmọ́ àtijáwọ́ á wá dogun!

Tóò, báwo wá la ṣe lè borí àwọn àṣà tí kò dáa, ká sì fi èyí tó dáa rọ́pò wọn? Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlànà Bíbélì mẹ́ta tó máa ràn wá lọ́wọ́.