Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Káfíńtà”

“Káfíńtà”

Bí Ìgbésí Ayé Àti Àsìkò Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Ṣe Rí

“Káfíńtà”

“Èyí ha kọ́ ni ọmọkùnrin káfíńtà náà?”—MÁTÍÙ 13:55.

KÌ Í ṣe “ọmọkùnrin káfíńtà” nìkan ni wọ́n mọ Jésù sí, wọ́n tún mọ̀ ọ́n sí “káfíńtà.” (Máàkù 6:3) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Jósẹ́fù, ìyẹn bàbá tó gbà á tọ́ ló ti kọ́ iṣẹ́ yìí.

Ìmọ̀ wo ló yẹ kí Jésù ní, àwọn irinṣẹ́ wo ló sì gbọ́dọ̀ mọ̀ ọ́n lò dáadáa nígbà tó ń ṣiṣẹ́ káfíńtà? Àwọn nǹkan wo ló ṣeé ṣe kó ti bá àwọn ará Násárétì ṣe? Báwo sì ni iṣẹ́ ìfigi-ṣe-nǹkan tó kọ́ níbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe ní ipa lórí rẹ̀ nígbà tó yá?

Iṣẹ́ Ìdílé Nínú àwòrán tó wà nísàlẹ̀ yìí, bàbá kan ń kọ́ ọmọkùnrin rẹ̀ àgbà bó ṣe lè lo ohun ìluhò lọ́nà tó dára, tí irinṣẹ́ náà kò sì ní pa á lára. Ọmọkùnrin rẹ̀ kékeré ń fetí sílẹ̀, ó sì ń wo ohun tí wọ́n ń ṣe.

Nǹkan bí ọmọ ọdún méjìlá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún làwọn ọmọkùnrin sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ iṣẹ́ yìí. Ọ̀dọ̀ bàbá wọn ni wọ́n ti sábà máa ń kọ́ ọ. Ó máa ń gba ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n tó kọ́ iṣẹ́ yìí parí, àwọn ọmọkùnrin yìí sì gbọ́dọ̀ sapá gan-an kí wọ́n lè ní ìmọ̀ tó yẹ kéèyàn ní kó tó lè di káfíńtà. Fojú inú wo ọ̀pọ̀ àkókò tí Jósẹ́fù á ti lò pẹ̀lú Jésù, bó ṣe ń bá a ṣiṣẹ́, tó ń bá a sọ̀rọ̀, tó sì ń kọ́ ọ lóhun pàtàkì tó yẹ kó mọ̀. Ẹ wo bí inú Jósẹ́fù á ṣe dùn tó bó ṣe ń wo Jésù tó ń fi igi dárà!

Ìmọ̀, Okun àti Òye Ṣe Kókó Káfíńtà kan ní láti mọ irú igi tó yẹ kó lò. Ó lè lo àwọn igi bí, igi sípírẹ́sì, óákù, kédárì, síkámórè àti igi ólífì. Àmọ́, kò sí ìsọ̀ pákó ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní níbi tí káfíńtà kan ti lè lọ ra igi tó máa lò. Kàkà bẹ́ẹ̀, òun fúnra rẹ̀ ló máa lọ sínú igbó kìjikìji, tó máa wá igi tó fẹ́ lò, tí á gé e lulẹ̀, tí á sì gbé igi ńlá náà wá sí ṣọ́ọ̀bù rẹ̀.

Kí ni káfíńtà kan lè fi igi tó gé ṣe? Ó lè lo ọ̀pọ̀ àkókò láti fi igi náà bá àwọn èèyàn kọ́lé. Á la àwọn igi tó máa fi ṣe òrùlé ilé, èyí tó máa fi ṣe àtẹ̀gùn inú ilé, á tún ṣe àwọn ilẹ̀kùn, fèrèsé àtàwọn férémù tó máa fi gbé àwọn ògiri ilé ró.

Káfíńtà tún máa ń ṣe àwọn ohun èlò ilé. Àwọn àwòrán oní-nọ́ńbà yìí jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan náà. Kọ́bọ́ọ̀dù tó ní àwọn àyè téèyàn lè kó nǹkan sí, tó sì tún ní àwọn ilẹ̀kùn (1); àwọn àpótí (2), àwọn àga (3), àtàwọn tábìlì (4) onírúurú àti ibi tí wọ́n máa ń gbé ọmọ jòjòló sí. Wọ́n máa ń figi ṣe ọ̀ṣọ́ tó fani mọ́ra sára àwọn kan lára nǹkan tí wọ́n ṣe yìí. Káfíńtà lè fi ìda oyin, nǹkan olómi tó ń dán gbinrin tàbí òróró kun nǹkan tó ṣe náà kó bàa lè lẹ́wà, kó sì lá lò pẹ́.

Káfíńtà tún máa ń ṣe irinṣẹ́ táwọn àgbẹ̀ ń lò, irú bí, àjàgà (5) tó máa gbẹ́ jáde látinú igi ńlá, títí kan amúga, réèkì àti ṣọ́bìrì (6). Àwọn ohun èlò ìtúlẹ̀ (7) tí ó figi ṣe gbọ́dọ̀ lágbára, torí inú ilẹ̀ tó le làwọn irin tó wà lẹ́nu wọn máa wọ̀. Ó máa ń fi igi ṣe ọkọ̀ (8) àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin, ó tún máa ń ṣe sípóòkì tó lágbára fún àgbá kẹ̀kẹ́, èyí tó ń gbé ọkọ̀ náà ṣiṣẹ́. Ara iṣẹ́ rẹ̀ tún lè jẹ́ ṣíṣe àtúnṣe àwọn ohun èlò ilé, irinṣẹ́ àwọn àgbẹ̀ àtàwọn ọkọ̀ tí wọ́n figi ṣe.

Ṣé o lè fojú inú wo bí Jésù ṣe máa rí nítorí iṣẹ́ tó ń ṣe yìí? Fojú inú wo bí oòrùn Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé ṣe ń pa Jésù, iṣan rẹ̀ ń lágbára sí i bí ọdún ṣe ń gorí ọdún nídìí iṣẹ́ alágbára tó ń ṣe, bẹ́ẹ̀ sì ni àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ ń le sí i bó ṣe ń di igi tí ara rẹ̀ kò dán mú tó sì ń fi àáké gégi, tó ń lo òòlù àti ayùn.

Ohun Tó fi Ṣàpèjúwe Jésù fi àwọn nǹkan èlò táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ṣàlàyé àwọn òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jinlẹ̀ lọ́nà tó rọrùn. Ṣé látinú iṣẹ́ káfíńtà tó kọ́ ló ti mú àwọn kan lára àpèjúwe rẹ̀? Jẹ́ ká wo àwọn nǹkan díẹ̀ tó fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó rí bẹ́ẹ̀. Ó sọ fún àwọn èèyàn tó ń bá sọ̀rọ̀ nígbà kan pé: “Èé ṣe tí ìwọ fi wá ń wo èérún pòròpórò tí ó wà nínú ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n tí o kò ronú nípa igi ìrólé tí ó wà nínú ojú ìwọ fúnra rẹ?” Káfíńtà mọ bí igi ìrólé ṣe tóbi tó. (Mátíù 7:3) Nígbà tó yá, Jésù tún sọ fún àwùjọ kan pé: “Kò sí ènìyàn tí ó ti fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun ìtúlẹ̀, tí ó sì ń wo àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn tí ó yẹ dáadáa fún ìjọba Ọlọ́run.” Ó ṣeé ṣe kó ti ṣe ọ̀pọ̀ ohun èlò ìtúlẹ̀. (Lúùkù 9:62) Lákòókò kan tí Jésù fìfẹ́ pe àwọn èèyàn, ó mẹ́nu kan ohun èlò kan tí àwọn káfíńtà ṣe. Jésù sọ pé: “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, . . . Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Mátíù 11:29, 30) Kò sí iyè méjì pé Jésù mọ béèyàn ṣe ń ṣe àjàgà tí kì í ṣe ẹran léṣe, àmọ́ èyí tó jẹ́ ti “inú rere,” tàbí èyí tó ṣe déédéé.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe làwọn alátakò Jésù ń pẹ̀gàn rẹ̀ nígbà tí wọ́n ń pè é ní “ọmọkùnrin káfíńtà.” Pẹ̀lú gbogbo rẹ̀ náà, àǹfààní ńlá làwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní àti ti òde òní kà á sí láti máa tẹ̀ lé onírẹ̀lẹ̀ tó jẹ́ káfíńtà rí yìí.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Irinṣẹ́ Tó Wà Nínú Àpótí Káfíńtà

Káfíńtà ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní bíi Jésù ní láti mọ bó ṣe lè lo àwọn irinṣẹ́ tó wà nínú àwòrán yìí. Ayùn (1) jẹ́ nǹkan tí wọ́n fi igi ṣe férémù rẹ̀, ó sì ní abẹ onírin èyí tí káfíńtà lè fi gé nǹkan. Ó máa ń lo irin kọdọrọ (square) láti fi (2) mọ̀ bóyá igi kan ṣe dáadáa, á sì lo púlọ́ọ̀mù (3) láti wo bó ṣe tọ́ sí. Nínú àpótí yìí, irinṣẹ́ tí wọ́n fi ń wọn bí nǹkan ṣe ga tó (4), rúlà onígi (5), ìfági tí ẹnu rẹ̀ mú, tó ní abẹ onírin téèyàn lè fi dán ara igi (6), àti àáké (7) téèyàn lè fi gé igi.

Káfíńtà máa ń fi ìgbẹ́gi (8) àti ohun ìgbẹ́hò (9) ṣe ọnà sára igi. Lórí àpótí irinṣẹ́ náà, òòlù onígi kan tí wọ́n fi irin ṣe orí rẹ̀ wà níbẹ̀, (10) wọ́n máa fi ń gbá igi kékeré wọnú ihò tàbí kí wọ́n fi gbá nǹkan tí wọ́n fẹ́ fi lu ihò. Ayùn kékeré kan tún wà níbẹ̀ (11), ọ̀bẹ tí wọ́n fi ń sàmì (12) tí wọ́n bá fẹ́ gbẹ́ nǹkan àtàwọn ìṣó mélòó kan wà níbẹ̀ (13). Níwájú àpótí irinṣẹ́ náà, òòlù onírin kan wà níbẹ̀ (14) àti àáké kékeré (15) tí wọ́n fi ń ṣí èèpo igi kúrò. Lórí àpótí, ọ̀bẹ kan wà níbẹ̀ (16) àti onírúurú ohun tí wọ́n fi ń dá ihò (17) sára igi. Irin tí wọ́n fi ń lu ihò tó dà bí ọfà (18) wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àpótí náà.