Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọn Kò Bẹ̀rù Òpin Ayé Mọ́

Wọn Kò Bẹ̀rù Òpin Ayé Mọ́

Wọn Kò Bẹ̀rù Òpin Ayé Mọ́

NÍGBÀ tó kù díẹ̀ kí ọdún 1980 wọlé dé, Gary àti Karen gbà pé òpin ayé ti sún mọ́lé. Nítorí náà, wọ́n kó kúrò ní ìlú, wọ́n sì lọ sí ìgbèríko, wọ́n pinnu pé àwọn fúnra àwọn làwọn á máa ṣe gbogbo ohun táwọn bá nílò. Wọ́n fẹ́ la òpin ayé já.

Kí wọ́n bàa lè gba gbogbo ìmọ̀ tí wọ́n nílò, wọ́n ra àwọn ìwé, wọ́n lọ fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn àpérò, wọ́n sì rí i pé àwọn bá ọ̀pọ̀ èèyàn sọ̀rọ̀. Wọ́n gbin ẹ̀fọ́ sínú ọgbà, wọ́n sì tún ní àádọ́ta igi eléso. Wọ́n kó àwọn irúgbìn àti irinṣẹ́ jọ. Wọ́n kọ́ bá a ṣe ń gbin nǹkan ọ̀gbìn àti bí wọ́n ṣe ń tọ́jú oúnjẹ. Ọ̀rẹ́ wọn kan kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa pa ẹran tí wọ́n á sì máa tọ́jú rẹ̀. Karen kọ́ bó ṣe lè dá àwọn ewéko àtàwọn ìtàkùn mọ̀ nínú igbó kí wọ́n lè máa jẹ wọ́n nígbà tí kò bá sí oúnjẹ mọ́. Gary kọ́ bó ṣe lè máa fi àgbàdo ṣe epo téèyàn lè fi sun nǹkan, ó kọ́ bí wọ́n ṣe ń fi irin ṣe àdògán, wọ́n sì kọ́ ilé kan tí kò ní ohun amáyédẹrùn.

Karen sọ pé: “Nítorí ipò burúkú tí ayé wà nígbà yẹn, mo rò pé ìgbà ọ̀làjú kò ní pẹ́ pa run.” Gary ṣàlàyé pé: “Bíi ti àwọn ọ̀dọ́ yòókù, mo sapá láti mú kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, Ogun Vietnam àti ìwà ìbàjẹ́ kúrò. Àmọ́, kò pẹ́ tí mo fi rí ìjákulẹ̀. Lójú mi, ó jọ pé ńṣe ni aráyé máa fọwọ́ ara wọn pa ara wọn run.”

Gary sọ pé, “Lálẹ́ ọjọ́ kan, mo ráyè, ni mo bá gbé Bíbélì, mo sì kà á láti Mátíù dé Ìṣípayá. Ní alẹ́ ọjọ́ mẹ́rin tó tẹ̀ lé e, mo tún un kà. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́ lọ́jọ́ karùn-ún, mo sọ fún Karen pé: ‘Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí. Ọlọ́run kò ní pẹ́ fọ ayé yìí mọ́. A ní láti wá àwọn tó máa là á já.’” Gary àti Karen bẹ̀rẹ̀ sí í lọ láti ẹ̀sìn kan sí òmíràn, wọ́n ń wá àwọn èèyàn tó fẹ́ múra sílẹ̀ de òpin ayé.

Kò pẹ́ ni ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sí ẹnu ọ̀nà wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Karen sọ pé “Inú mi dùn gan-an nítorí pé Bíbélì ni wọ́n ń ṣàlàyé fún mi. Mo ti ń fẹ́ mọ òtítọ́ nípa àkókò òpin. Mo sì ti rí i nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Ìrètí tó dájú wà fún wa lọ́jọ́ ọ̀la. Èyí tó ṣe pàtàkì ni pé mo bẹ̀rẹ̀ sí í ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Bàbá mi ọ̀run, Ẹlẹ́dàá àti Ọlọ́run ayé àtọ̀run.”

Gary sọ pé: “Ìgbésí ayé mi wá nítumọ̀ gidi. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mò ń gbádùn rẹ̀ nìṣó. Mo ka àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, mo ṣàyẹ̀wò ẹ̀rí tó fi hàn pé ó ń ṣẹ, ó sì dá mi lójú pé Ọlọ́run yóò ṣe nǹkan kan láìpẹ́. Mo ronú pé, ‘Ìgbésí ayé tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbé ló yẹ káwọn èèyàn máa múra sílẹ̀ fún, kì í ṣe àjálù.’” Ní báyìí, Gary àti Karen ti wá ń fojú tó dára wo ọjọ́ ọ̀la. Dípò kí wọ́n máa ṣàníyàn nípa òpin ayé, ọkàn wọn balẹ̀ pé Ọlọ́run yóò mú gbogbo ìṣòro tó ń bá aráyé fínra kúrò, yóò sì sọ ayé di Párádísè.

Kí ni Gary àti Karen ń ṣe nísinsìnyí, ìyẹn lẹ́yìn nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n? Karen sọ pé: “Mo ń mú kí ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ mi nínu rẹ̀, máa pọ̀ sí i, mo sì ń ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun kan náà. Èmi àti Gary ń ran ara wa lọ́wọ́ bá a ti ń mú kí ìdílé wa máa lágbára sí i, tá a sì ń jọ́sìn Ọlọ́run níṣọ̀kan. À ń sapá láti máa ṣe nǹkan létòlétò, a kò lépa ọrọ̀ ká lè gbájú mọ́ ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́.”

Gary fi kún un pé: “Mo máa ń gbàdúrà déédéé pé kí ìjọba Ọlọ́run dé, kó sì mú ìtura bá ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn. Gbogbo ìgbà tí mo bá ń sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn, mo máa ń gbà á ládùúrà pé kí n lè mú kí ẹnì kan, ó kéré tán, ní ìrètí tó wà nínú Bíbélì. Ní ohun tó lé ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nísinsìnyí, Jèhófà ti fi àánú hàn sí mi, ó ti dáhùn àdúrà yẹn. Èmi àti Karen gbà gbọ́ pé Jèhófà yóò mú àyípadà ńlá bá ayé yìí láìpẹ́, àmọ́ a kò bẹ̀rù òpin ayé mọ́.”—Mátíù 6:9, 10; 2 Pétérù 3:11, 12.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Gary àti Karen ń gbádùn ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ohun rere tó máa bá ayé lọ́jọ́ iwájú