Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Ń Ba Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lẹ́rù?

Kí Ló Ń Ba Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lẹ́rù?

Kí Ló Ń Ba Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lẹ́rù?

“Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ dìgbà tó o bá jẹ́ onísìn kó o tó mọ̀ pé aráyé máa tó kàgbákò.”—STEPHEN O’LEARY, IGBÁ KEJÌ Ọ̀JỌ̀GBỌ́N, NÍ YUNIFÁSÍTÌ SOUTHERN CALIFORNIA. a

ǸJẸ́ o gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí? Ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa ṣàgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ìdí táwọn èèyàn fi ń bẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ṣùgbọ́n wọ́n á tún jẹ́ kó o mọ ìdí tó fi yẹ kí ọkàn rẹ balẹ̀ pé ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé kò ní dópin. Ìdí wà tá a fi lè ní in lọ́kàn pé nǹkan á dára, láìwo ti àwọn nǹkan tó ń bani nínú jẹ́ tó o máa kà nípa wọn yìí.

Ìbẹ̀rù ogun runlérùnnà ń pọ̀ sí i. Lọ́dún 2007, ìwé ìròyìn náà, Bulletin of the Atomic Scientists, kìlọ̀ pé: “Ṣáájú ìgbà tí wọ́n ju àwọn bọ́ǹbù átọ́míìkì àkọ́kọ́ sí ìlú Hiroshima àti Nagasaki ni aráyé ti dojú kọ ewu ńlá.” Kí nìdí tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìwé ìròyìn náà sọ pé ní ọdún 2007, nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin [27,000] ohun ìjà runlérùnnà ló ṣì wà àti pé ẹgbàá [2,000] lára wọn ti wà ní sẹpẹ́ láti “ṣọṣẹ́ láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀.” Bí wọ́n bá yin ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn ohun ìjà náà, àjálù ńlá ló máa yọrí sí!

Ǹjẹ́ ìbẹ̀rù pé ogun runlérùnnà lè jà ti dín kù látìgbà yẹn? Ìwé ọdọọdún tó ń jẹ́ SIPRI, b c ti ọdún 2009 sọ pé, orílẹ̀-èdè Ṣáínà, Faransé, Rọ́ṣíà, Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ilẹ̀ Amẹ́ríkà, tí wọ́n ní ohun ìjà runlérùnnà tó pọ̀ jù lọ “ń kó ohun ìjà tuntun jọ tàbí kí wọ́n polongo pé àwọn máa ṣe bẹ́ẹ̀.” Àmọ́ ìwé náà sọ pé kì í ṣe àwọn orílẹ̀-èdè yẹn nìkan ló ní ohun ìjà runlérùnnà. Àwọn aṣèwádìí fojú bù ú pé orílẹ̀-èdè Íńdíà, Pakistan àti Ísírẹ́lì ní bọ́ǹbù runlérùnnà tó tó ọgọ́ta sí ọgọ́rin. Wọ́n tún sọ pé, ohun ìjà tí iye rẹ̀ jẹ́ ẹgbàárin àti irínwó dín mẹ́jọ [8,392] ni wọ́n ti kó jọ kárí ayé, wọ́n kàn ń dúró de ìgbà tí wọ́n máa lò wọ́n ni!

Ojú ọjọ́ tó ń yí pa dà lágbàáyé lè fa àjálù. Ìwé ìròyìn àwọn onímọ̀ átọ́míìkì, ìyẹn Bulletin of the Atomic Scientists sọ pé, “Ewu tí ojú ọjọ́ tó ń yí pa dà lágbàáyé lè fà kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí èyí tí ohun ìjà runlérùnnà lè fà.” Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún irú bíi, Stephen Hawking, ọ̀jọ̀gbọ́n ní Yunifásítì Cambridge àti Ọ̀gbẹ́ni Martin Rees, tó jẹ́ Ọ̀gá ní Trinity College ti Yunifásítì Cambridge, ṣe àsọtúnsọ ìkìlọ̀ wọ̀nyẹn. Wọ́n sọ pé àṣìlò ìmọ̀ ẹ̀rọ àti ìpalára táwọn èèyàn ti ṣe fún àyíká wa lè yí ìgbésí ayé wa lórí ilẹ̀ ayé pa dà pátápátá tàbí kó fòpin sí ìgbà ọ̀làjú tá a wà yìí.

Àsọtẹ́lẹ̀ ìparun ń yọ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́nu. Tó o bá tẹ ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, “end of the world” ìyẹn òpin ayé àti ọdún “2012” sínú kọ̀ǹpútà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìsọfúnni ló máa gbé wá pé òpin ayé máa dé lọ́dún 2012. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọdún 2012 ni kàlẹ́ńdà àwọn Máyà ayé àtijọ́ tí wọ́n ń pè ní “Long Count,” máa parí. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bẹ̀rù pé èyí ń sọ fún wa lọ́nà kan ṣá pé òpin máa dé bá ìgbà ọ̀làjú wa yìí.

Ọ̀pọ̀ onísìn gbà pé Bíbélì kọ́ni pé ayé yìí máa pa run. Wọ́n sọ pé wọ́n máa kó àwọn olóòótọ́ tí wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ lọ sí ọ̀run, tí wọ́n á sì fi àwọn ọmọ aráyé yòókù sílẹ̀ láti jìyà nínú ayé onídàrúdàpọ̀ tàbí kí wọ́n jù wọ́n sínú iná ọ̀run àpáàdì.

Ǹjẹ́ òótọ́ ni Bíbélì sọ pé ayé yóò pa run pátápátá? Àpọ́sítélì Jòhánù kìlọ̀ fún wa pé, “Ẹ má ṣe gba gbogbo àgbéjáde onímìísí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn àgbéjáde onímìísí wò láti rí i bóyá wọ́n pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (1 Jòhánù 4:1) Kàkà kó o kàn gba ohun táwọn èèyàn ń sọ gbọ́, o ò ṣe ṣí Bíbélì kó o sì fúnra rẹ wo ohun tó sọ nípa òpin ayé. Ohun tó kọ́ni lè yà ọ́ lẹ́nu.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀rọ̀ yìí wá látinú àpilẹ̀kọ kan tó sọ nípa bí àwọn àjálù ṣe ń mú káwọn èèyàn máa sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ìparun tó ń bọ̀, wọ́n gbé e jáde lórí ìkànnì MSNBC, October 19, 2005.

b SIPRI dúró fún orúkọ àjọ tó ń ṣèwádìí nípa ọ̀ràn àlàáfíà ayé, ìyẹn Stockholm International Peace Research Institute.

c Àwọn tó kọ ìròyìn tó wà nínú ìwé ọdọọdún náà, SIPRI Yearbook 2009 ni ọ̀gbẹ́ni Shannon N. Kile, tó jẹ́ olùṣèwádìí àgbà àti olórí àwọn tó ń rí sí ọ̀ràn ohun ìjà runlérùnnà ti àjọ SIPRI Arms Control and Non-proliferation Programme, ọ̀gbẹ́ni Vitaly Fedchenko, tó jẹ́ olùṣèwádìí nípa ohun ìjà runlérùnnà ti àjọ SIPRI Arms Control and Non-proliferation Programme àti ọ̀gbẹ́ni Hans M. Kristensen, olùdarí ìsọfúnni nípa ohun ìjà runlérùnnà fún àwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ilẹ̀ Amẹ́ríkà.

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]

Fọ́tò eruku bọ́ǹbù: U.S. National Archives photo; fọ́tò ìjì líle: WHO/League of Red Cross and U.S. National Archives photo