Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Mo Lè Rí Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Máa Tù Mí Nínú Nínú Bíbélì?

Ṣé Mo Lè Rí Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Máa Tù Mí Nínú Nínú Bíbélì?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bẹ́ẹ̀ ni. (Róòmù 15:4) Ẹ jẹ́ ká wo díè lára àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ti tu ọ̀pọ̀ nínú lásìkò tí wọ́n ní ìṣòro tó ń kó wọ́n lọ́kàn sókè.

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa

 Ìṣòro tó lágbára

 Sáàmù 23:4: “Bí mo tilẹ̀ ń rìn nínú àfonífojì tó ṣókùnkùn biribiri, mi ò bẹ̀rù ewukéwu, nítorí o wà pẹ̀lú mi.”

 Ohun tó túmọ̀ sí: Tó o bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, tó o sì ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, wàá nígboyà láti kojú àwọn ìṣòro tó bá yọjú.

 Fílípì 4:13: “Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.”

 Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run lè fún ẹ lókun láti fara da ìṣòro èyíkéyìí tó o bá dojú kọ.

 Ikú ẹni tó o nífẹ̀ẹ́

 Oníwàásù 9:10: “Kò sí iṣẹ́ tàbí èrò tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú Isà Òkú, ibi tí ìwọ ń lọ.”

 Ohun tó túmọ̀ sí: Àwọn tó ti kú ò jẹ̀rora, wọn ò sì lè pa wá lára torí pé wọn ò mọ nǹkan kan mọ́.

 Ìṣe 24:15: “Àjíǹde . . . yóò wà.”

 Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run lè jí àwọn èèyàn wa tó ti kú dìde.

 Kéèyàn máa dára ẹ̀ lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ

 Sáàmù 86:5: “Nítorí pé ẹni rere ni ọ́, Jèhófà, a o sì ṣe tán láti dárí jini; ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí gbogbo àwọn tó ń ké pè ọ́ pọ̀ gidigidi.”

 Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run máa ń dárí ji àwọn tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, tí wọ́n sì pinnu pé àwọn ò ní ṣe irú àṣìṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.

 Sáàmù 103:12: “Bí yíyọ oòrùn ṣe jìnnà sí wíwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.”

 Ohun tó túmọ̀ sí: Tí Ọlọ́run bá ti dárí jì wá, kì í rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́. Kì í sì í fi àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn jẹ wá níyà.

 Ìbànújẹ́

 Sáàmù 31:7: “O ti rí ìpọ́njú mi; o mọ ìdààmú ńlá tó bá mi.”

 Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run mọ gbogbo ohun tó ò ń bá yí. Ó mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ báwọn míì ò tiẹ̀ mọ̀ ọ́n.

 Sáàmù 34:18: “Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn; ó ń gba àwọn tí àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn là.”

 Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa dúró tiẹ̀ lásìkò tí inú ẹ ò bá dùn. Ó lè fún ẹ lókun láti fara da ìnira.

 Àìsàn

 Sáàmù 41:3: “Jèhófà yóò fún un lókun lórí ibùsùn àìsàn rẹ̀.”

 Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run lè fún ẹ lókun kó o lè fara da àìsàn tó lágbára, á sì tún fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀. Bákan náà, ó lè fún ẹ ní ọgbọ́n tó o nílò kó o lè ṣèpinnu tó tọ́.

 Àìsáyà 33:24: “Kò sí ẹnì kankan tó ń gbé ibẹ̀ tó máa sọ pé: “Ara mi ò yá.’”

 Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run ṣèlérí pé láìpé gbogbo èèyàn máa gbádùn ìlera tó jí pépé.

 Ìdààmú ọkàn

 Sáàmù 94:19: “Nígbà tí àníyàn bò mí mọ́lẹ̀, o tù mí nínú, o sì tù mí lára.”

 Ohun tó túmọ̀ sí: Tá a bá yíjú sí Ọlọ́run nígbà tá a bá ní ìdààmú ọkàn, ó máa fi wá lọ́kàn balẹ̀.

 1 Pétérù 5:7: “Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, torí ó ń bójú tó yín.”

 Ohun tó túmọ̀ sí: Ó máa ń dun Ọlọ́run tó bá rí i tá à ń jìyà. Ó sì rọ̀ wá pé ká gbàdúrà sí òun nípa àwọn ìṣòro wa.

 Ogun

 Sáàmù 46:9: “Ó ń fòpin sí ogun kárí ayé.”

 Ohun tó túmọ̀ sí: Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ogun táwọn èèyàn ń jà.

 Sáàmù 37:11, 29: “Àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóò jogún ayé, inú wọn yóò sì máa dùn jọjọ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà. . . . Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.”

 Ohun tó túmọ̀ sí: Àwọn olódodo máa gbádùn àlááfíà títí láé lórí ilẹ̀ ayé.

 Àníyàn nípa ọjọ́ iwájú

 Jeremáyà 29:11: “‘Mo mọ èrò tí mò ń rò nípa yín dáadáa,’ ni Jèhófà wí, ‘èrò àlàáfíà, kì í ṣe ti àjálù, láti fún yín ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.’”

 Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run fi dá àwọn èèyàn ẹ̀ lójú pé kí wọ́n fọkàn balẹ̀ ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.

 Ìfihàn 21:4: “Ó máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá lọ.”

 Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run ṣèlérí pé láìpẹ́ àwọn ohun búburú tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí máa di ohun àtijọ́.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Ka àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?