Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìgbéyàwó?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìgbéyàwó?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, ó so wọ́n pọ̀, wọ́n sì di tọkọtaya. Ọlọ́run fi ìgbéyàwó lọ́lẹ̀ kó lè jẹ́ àjọṣe pàtàkì láàárín ọkùnrin àti obìnrin, kó sì di ìpìlẹ̀ tí ìdílé dúró lé lórí.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; 2:18.

 Ọlọ́run fẹ́ kí tọkọtaya máa láyọ̀. (Òwe 5:18) Nínú Bíbélì, ó pèsè àwọn ìtọ́ni táá máa darí ìgbéyàwó àti àwọn ìlànà táá jẹ́ kó yọrí sí rere.

Nínú àpilẹ̀kọ yìí

 Ìlànà wo ni Ọlọ́run fún àwọn tó ṣègbéyàwó?

 Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti mú kí ìgbéyàwó jẹ́ ọ̀nà tí ọkùnrin àti obìnrin á fi máa gbé pọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Ọlọ́run ò fọwọ́ sí kíkó obìnrin jọ, bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀, tàbí kí ọkùnrin àti obìnrin jọ máa gbé pọ̀ láìṣègbéyàwó. (1 Kọ́ríńtì 6:9; 1 Tẹsalóníkà 4:3) Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé ìlànà tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó ni kí wọ́n máa tẹ̀ lé.​—Máàkù 10:6-8.

 Lójú Ọlọ́run, ìgbéyàwó jẹ́ àjọṣe tó wà títí lọ. Nígbà tí ọkùnrin àti obìnrin bá ṣègbéyàwó, wọ́n á ṣèlérí pé àwọn máa jẹ́ olóòótọ́ síra wọn àti pé wọn ò ní ya ara wọn níwọ̀n ìgbà tí àwọn méjèèjì bá fi jọ wà láàyè. Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n pa àdéhùn yẹn mọ́.​—Máàkù 10:9.

 Kí ni Bíbélì sọ nípa ìpínyà àti ìkọ̀sílẹ̀?

 Àwọn ìgbà kan lè wà tí tọkọtaya lè má wà pa pọ̀, irú bí ìgbà tí ọ̀kan lára wọn bá rìnrìn àjò kó lè lọ bójú tó ohun àìròtẹ́lẹ̀ tó kan ìdílé wọn. Ṣùgbọ́n Bíbélì sọ pé kí wọ́n má ṣe pínyà torí ìṣòro ìgbéyàwó. Dípò tí wọ́n á fi pínyà, Bíbélì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n yanjú ìṣòro náà.​—1 Kọ́ríńtì 7:10.

 Àgbèrè nìkan ṣoṣo ni Bíbélì sọ pé ó lè fa ìkọ̀sílẹ̀. (Mátíù 19:9) Torí náà, bí tọkọtaya bá pinnu láti pínyà tàbí kọ ara wọn sílẹ̀ torí ìdí èyíkéyìí yàtọ̀ sí àgbèrè, kò sí èyíkéyìí nínú wọ́n tó lómìnira láti fẹ́ ẹlòmíì sọ́nà tàbí kó bá a ṣègbéyàwó.​—Mátíù 5:32; 1 Kọ́ríńtì 7:11.

 Ṣó yẹ kí tọkọtaya forúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin kó tó ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run?

 Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn Kristẹni pa òfin ìjọba nípa ìgbéyàwó mọ́. (Títù 3:1) Tó bá ṣeé ṣe fún tọkọtaya láti forúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, ìyẹn á fi hàn pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ àti ìlànà Ọlọ́run tó sọ pé kí ìgbéyàwó jẹ́ àdéhùn tó wà pẹ́ títí. a

 Kí ni Bíbélì sọ pé ó jẹ́ ojúṣe ọkọ àti aya nínú ìgbéyàwó?

  •   Ojúṣe tọkọtaya. Tọkọtaya gbọ́dọ̀ máa bọ̀wọ̀ fúnra wọn, kí wọ́n sì máa fi ìfẹ́ bára wọn lò. (Éfésù 5:33) Kí wọ́n má fi ìbálòpọ̀ du ara wọn, kí wọ́n sì máa ṣe é tìfẹ́tìfẹ́. Bákan náà, kí wọ́n yẹra fún ìwà àìṣòótọ́ èyíkéyìí. (1 Kọ́ríńtì 7:3; Hébérù 13:4) Tí wọ́n bá bímọ, kí wọ́n jọ fọwọ́sowọ́pọ̀ tọ́ wọn.​—Òwe 6:20.

     Bíbélì ò ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa bí tọkọtaya á ṣe máa ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àtàwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ míì nínú ilé. Wọ́n lè jọ pinnu ohun tí wọ́n bá mọ̀ pé ó máa rọrùn fún ìdílé wọn.

  •   Ojúṣe ọkọ. Bíbélì sọ pé “ọkọ ni orí aya rẹ̀.” (Éfésù 5:23) Ọkọ jẹ́ orí ní ti pé òun ló gbọ́dọ̀ máa darí ìdílé rẹ̀ kó sì máa ṣe ìpinnu táá ṣe ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ láǹfààní.

     Ó gbọ́dọ̀ rí i pé òun pèsè ohun tí á mú kí wọ́n ní ìlera tó dáa, kí wọ́n láyọ̀, kí wọ́n sì sún mọ́ Ọlọ́run. (1 Tímótì 5:8) Tóun àti ìyàwó rẹ̀ bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀, tó sì ń fara balẹ̀ gbé èrò rẹ̀ àtí bí nǹkan ṣe rí lára ìyàwó rẹ̀ yẹ̀ wò tó bá ń ṣe ìpinnu, á tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun mọyì àwọn ànímọ́ àti òye tí ìyàwó rẹ̀ ní. (Òwe 31:11, 28) Bíbélì sọ pé kí ọkọ máa fi ìfẹ́ ṣe ojúṣe rẹ̀ nínú ìdílé.​—Kólósè 3:19.

  •   Ojúṣe aya. Bíbélì sọ pé “kí aya ni ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” (Éfésù 5:33) Inú Ọlọ́run máa ń dùn tí aya bá fi ọ̀wọ̀ hàn fún ojúṣe ọkọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé.

     Ojúṣe rẹ̀ ni pé kó máa ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn, kó máa ràn án lọ́wọ́ kó lè máa ṣe ìpinnu tó dáa, kó sì máa kọ́wọ́ tì í bó ṣe ń bójú tó ipò orí rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Bíbélì sọ̀rọ̀ tó dáa nípa aya tó bá ṣe ojúṣe pàtàkì tó jẹ́ tiẹ̀ nínú ìgbéyàwó.​—Òwe 31:10.

 Ṣé Ọlọ́run sọ pé káwọn tó ṣègbéyàwó lóde òní bímọ?

 Rárá o. Nígbà àtijọ́, Ọlọ́run pàṣẹ pé kí àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bímọ. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 9:1) Ṣùgbọ́n àṣẹ yẹn ò sí fáwọn Kristẹni. Jésù ò pàṣẹ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun bímọ. Kò sì sí èyíkéyìí lára àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn tó sọ pé tọkọtaya gbọ́dọ̀ bímọ. Tọkọtaya lo máa pinnu bóyá àwọn máa bímọ tàbí àwọn ò ṣe bẹ́ẹ̀.

 Báwo ni Bíbélì ṣe lè ran ìdílé mi lọ́wọ́?

 Àwọn ìlànà inú Bíbélì lè ran tọkọtaya lọ́wọ́ kí ìgbéyàwó wọn lè ní ìbẹ̀rẹ̀ tó dáa. Ìlànà Bíbélì tún lè ran tọkọtaya lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa ní ìṣòro tàbí kí wọ́n lè borí rẹ̀.

 Ìlànà Bíbélì lè ran tọkọtaya lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa . . .

a Tó o bá fẹ́ mọ ojú tí Bíbélì fi wo ìgbéyàwó ti ìbílẹ̀, wo Ilé Ìṣọ́ October 15, 2006, ojú ìwé 21, ìpínrọ̀ 12.