Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ Ìdẹwò?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ Ìdẹwò?

 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nígbà tí mo bá fẹ́ ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tó burú ló máa ń wà lọ́kàn mi.” (Róòmù 7:​21) Ṣé ó ti ṣe ẹ́ bẹ́ẹ̀ rí? Tó bá ti ṣe ẹ́ rí, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ bí wàá ṣe kọ ìdẹwò láti ṣe ohun tí kò tọ́ tó ń wá sí ẹ lọ́kàn.

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀

 Táwọn ojúgbà ẹ bá ń fúngun mọ́ ẹ pé kó o ṣe ohun táwọn ń ṣe, ìdẹwò dé nìyẹn. Kódà, Bíbélì sọ pé “ẹgbẹ́ búburú ń ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Táwọn míì bá ń fúngun mọ́ ẹ pé kó o máa ṣe bíi tàwọn tàbí tí ohun tó ò ń wò lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí íńtánẹ́ẹ̀tì ń wọ̀ ẹ́ lójú, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í ro èròkerò. Èyí lè mú kó o fẹ́ ṣe ohun tí kò tọ́, ó tiẹ̀ lè mú kó o “tẹ̀ lé ọ̀pọ̀ èèyàn láti hùwà ibi.”​—Ẹ́kísódù 23:2.

 “Torí pé o ṣáà fẹ́ káwọn míì fẹ́ràn ẹ tàbí kí wọ́n gba tìẹ, o lè lọ lọ́wọ́ sí ohunkóhun tí wọ́n bá ń ṣe.”​—Jeremy.

 Rò ó wò ná: Tó bá jẹ́ pé ojú táwọn míì fi ń wò ẹ́ lo máa ń rò ṣáá, kí nìdí tí ìyẹn fi lè jẹ́ kó túbọ̀ ṣòro fún ẹ láti borí ìdẹwò?​—Òwe 29:25.

 Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Má jẹ́ kí báwọn ọ̀rẹ́ ẹ ṣe ń fúngun mọ́ ẹ pé kó o ṣe bíi tàwọn mú kó o ṣe ohun tó ò fẹ́ ṣe.

 Ohun tó o lè ṣe

 Mọ ohun tó o gbà gbọ́. Tó ò bá mọ ohun tó o gbà gbọ́, ṣe ni wàá kàn dà bíi bèbí lọ́wọ́ àwọn èèyàn, wọ́n á wá máa fi ẹ́ ṣeré tó wù wọ́n. Ó sàn kó o tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì, pé: “Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú; ẹ di èyí tó dára mú ṣinṣin.” (1 Tẹsalóníkà 5:​21) Bí ohun tó o gbà gbọ́ bá ṣe túbọ̀ ń yé ẹ sí i, bẹ́ẹ̀ lá ṣe máa rọrùn fún ẹ láti máa fi ṣèwà hù, á sì túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti kọ̀ tí ẹnì kan tàbí ohun kan bá fẹ́ mú kó o ṣe ohun tó yàtọ̀.

 Rò ó wò ná: Kí ló mú kó o gbà pé ire ẹ làwọn ìlànà Ọlọ́run lórí ìwà híhù wà fún?

 “Mo ti kíyè sí i pé ìgbàkígbà tí mo bá dúró lórí ohun tí mo gbà gbọ́, tí mo sì kọ ìdẹwò, ṣe làwọn èèyàn máa ń túbọ̀ fi ọ̀wọ̀ mi wọ̀ mí.”​—Kimberly.

 Àpẹẹrẹ inú Bíbélì: Dáníẹ́lì. Ó ṣeé ṣe kí Dáníẹ́lì má tíì pé ọmọ ogún (20) ọdún nígbà tó “pinnu lọ́kàn rẹ̀” pé òun á máa ṣègbọràn sí àwọn òfin Ọlọ́run.​—Dáníẹ́lì 1:8.

Tó ò bá mọ ohun tó o gbà gbọ́, ṣe ni wàá kàn dà bíi bèbí lọ́wọ́ àwọn èèyàn, wọ́n á wá máa fi ẹ́ ṣeré tó wù wọ́n

 Mọ ibi tó o kù sí. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìgbà ọ̀dọ́,” ìyẹn àwọn ohun tọ́kàn èèyàn máa ń fà sí gan-an nígbà tó bá ṣì wà lọ́dọ̀ọ́. (2 Tímótì 2:​22) Kì í ṣe ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ nìkan ló ń tọ́ka sí, ó tún kan bó ṣe máa ń wu àwọn ọ̀dọ́ kí àwọn ojúgbà wọn gba tiwọn àti bó ṣe máa ń wù wọ́n láti ní òmìnira láti máa dá ṣe nǹkan kó tiẹ̀ tó di pé wọ́n dàgbà tó ẹni tó ń lómìnira.

 Rò ó wò ná: Bíbélì sọ pé “àdánwò máa ń dé bá kálukú nígbà tí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ bá fà á mọ́ra, tó sì tàn án jẹ.” (Jémíìsì 1:​14) Kí ni nǹkan tọ́kàn máa ń fà sí jù?

 “Má tanra ẹ jẹ tó bá dọ̀rọ̀ àwọn ohun tí ò dáa tọ́kàn ẹ máa ń fà sí jù. Ṣèwádìí nípa bó o ṣe lè borí irú àwọn ìdẹwò bẹ́ẹ̀, kó o sì ṣàkọsílẹ̀ àwọn kókó kan tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Wàá rí i pé nígbà míì tó o bá tún kojú ìdẹwò yẹn, wàá mọ bí wàá ṣe borí ẹ̀.”​—Sylvia.

 Àpẹẹrẹ inú Bíbélì: Dáfídì. Àwọn ìgbà kan wà tí Dáfídì jẹ́ káwọn míì mú un ṣe ohun tí ò dáa, kódà ìgbà míì wà tó ṣe ohun tọ́kàn ẹ̀ fà sí. Àmọ́ Dáfídì kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe ẹ̀, ó sì gbìyànjú láti ṣàtúnṣe. Ó gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Dá ọkàn mímọ́ sínú mi, Ọlọ́run, kí o sì fi ẹ̀mí tuntun sínú mi, èyí tó fìdí múlẹ̀.”​—Sáàmù 51:10.

 Gbé ìgbésẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, àmọ́ máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” (Róòmù 12:21) Ìyẹn fi hàn pé kì í ṣe dandan kó o kó sínú ìdẹwò. O lè pinnu pé ohun tó dáa lo máa ṣe.

 Rò ó wò ná: Báwo lo ṣe lè gbé ìgbésẹ̀, kó o sì rí i dájú pé ohun tó tọ́ lo ṣe dípò kó o ṣe ohun tí ò dáa tó o bá kojú ìdẹwò?

 “Mo máa ń ronú bó ṣe máa rí lára mi tí mo bá lọ ṣe ohun tí ò dáa tó ń dẹ mí wò. Ṣé ọkàn mi máa balẹ̀ ṣá? Ó lè jọ bẹ́ẹ̀, àmọ́ kò ní tọ́jọ́. Ṣé inú mi á dùn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn? Láéláé, ṣe ni nǹkan á tún burú sí i. Ṣó wá yẹ kí n firú ìyà yẹn jẹra mi? Rárá!”​—Sophia.

 Àpẹẹrẹ inú Bíbélì: Pọ́ọ̀lù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó gbà pé èrò tí ò dáa máa ń wá sí òun lọ́kàn, Pọ́ọ̀lù wá nǹkan ṣe sí i. Ó sọ pé: “Mò ń lu ara mi kíkankíkan, mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú.”​—1 Kọ́ríńtì 9:​27.

 Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Ìwọ lo máa pinnu ohun tó o máa ṣe tí ìdẹwò bá dé.

 Má gbàgbé pé ìdẹwò kì í tọ́jọ́. Melissa tó jẹ́ ọmọ ogún (20) ọdún sọ pé: “Nígbà tí mo wà nílé ẹ̀kọ́ girama, ọ̀pọ̀ nǹkan tó dà bí ìdẹwò ńlá ni ò jẹ́ nǹkankan mọ́ báyìí. Èyí máa ń jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé àwọn ìdẹwò tí mò ń kojú báyìí máa tó kọjá lọ, tí mo bá wá wẹ̀yìn wò lọ́jọ́ iwájú, màá rí i pé ṣe ni ayé mi túbọ̀ dáa sí i nígbà tí mo kọ̀ láti jẹ́ kí àwọn ìdẹwò yẹn mú mi.”