Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Mo Bá Ní Àìsàn tí Mò Ń Bá Fínra? (Apá 3)

Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Mo Bá Ní Àìsàn tí Mò Ń Bá Fínra? (Apá 3)

 Àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń nílera tó jí pépé, ara wọn sì máa ń yá gágá. Àmọ́ àwọn ọ̀dọ́ kan ní àìsàn tó le tí wọ́n ń bá fínra. Ṣé ohun tó ń ṣe ìwọ náà nìyẹn? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, ìrírí V’loria, Justin àti Nisa lè gbé ẹ ró. Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Wo bí wọ́n ṣe ń fara da àìsàn tí wọ́n ń bá fínra.

 V’loria

 Àtìgbà tí mo ti wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún (14) ni mo ti ní àrùn kan tó máa ń mú kí iṣan ara máa ro mí. Ìgbà tí màá fi pé ọmọ ogún (20) ọdún, mo ti ní àìsàn aromọléegun, àìsàn tó ń ba awọ ara jẹ́ tí wọ́n ń pè ní lupus, mo sì tún ní àrùn Lyme tó máa ń ba awọ ara àti iṣan ara jẹ́. Torí pé gbogbo ìgbà ló máa ń rẹ̀ mí, ó máa ń nira fún mi láti ṣe gbogbo ohun tó wù mí ṣe. Nígbà míì, ẹsẹ̀ mi méjèèjì máa ń rọ láti ìbàdí mi lọ sísàlẹ̀, ó sì máa ń di dandan kí n lo kẹ̀kẹ́ arọ.

 Ohun tó máa ń dùn mí ju ara mi tí ò yá lọ ni ìbànújẹ́ tó máa ń bá mi torí pé mi ò lè ṣe àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, bíi kí n kọ̀wé tàbí kí n ṣí ìdérí nǹkan. Tí mo bá rí àwọn ọmọdé tó ń rìn lọ, ó máa ń yà mí lẹ́nu pé èmi ò lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ó máa ń ṣe mí bíi pé kò sóhun tí mo mọ̀ ọ́n ṣe.

 Àmọ́ mo dúpẹ́ pé àwọn mọ̀lẹ́bí mi ò fi mí sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a jọ wà níjọ. Àwọn ará ìjọ wa sábà máa ń wá kí mi nílé, ìyẹn ni kì í jẹ́ kí n dá wà. Àwọn kan máa ń pè mí wá síbí àpèjẹ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn kí wọ́n máa gbé mi látorí kẹ̀kẹ́ arọ tí mo wà wọnú mọ́tò, kí wọ́n tún gbé mi jáde.

 Àwọn àgbàlagbà inú ìjọ wa náà ràn mí lọ́wọ́ gan-an torí àwọn náà ní àìsàn tí wọ́n ń bá fínra, ìyẹn sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi yé wọn. Wọn ò jẹ́ kí n banú jẹ́ tàbí kí n máa dá ara mi lẹ́bi torí pé mi ò lè ṣe bíi tàwọn tó kù. Tí mo bá lọ sípàdé tàbí tí mo lọ wàásù ni inú mi máa ń dùn jù. (Hébérù 10:25) Àwọn ìgbà yẹn ni mo máa ń mọ̀ pé kì í ṣe pé mo fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sáwọn tó kù náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mò ń ṣàìsàn.

 Mo máa ń fi sọ́kàn pé Jèhófà máa ń pèsè ohun tá a nílò ká lè máa fara da ìṣòro tá a ní. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé bí ẹni tá a jẹ́ lóde ara bá tiẹ̀ ń bà jẹ́, ẹni tí a jẹ́ ní inú lè máa “dọ̀tun láti ọjọ́ dé ọjọ́.” (2 Kọ́ríńtì 4:​16) Bó ṣe ń ṣe mí gan-an nìyẹn!

 Ronú nípa èyí: Tó o bá ń bá àìsàn kan tó le fínra, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì kó o máa ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́? Tí ìwọ ò bá ṣàìsàn, báwo lo ṣe lè ran ẹni tó ń ṣàìsàn lọ́wọ́?​—Òwe 17:17.

 Justin

 Mo ṣubú lulẹ̀, mi ò sì lè dìde. Ṣe ni àyà mi dì, mi ò sì lè kúrò lójú kan. Ní wọ́n bá sáré gbé mi lọ ilé ìwòsàn. Àwọn dókítà ò kọ́kọ́ mọ ohun tó ń ṣe mí. Àmọ́ nígbà tírú ẹ̀ tún ṣe mí ní ẹ̀ẹ̀melòó kan, wọ́n pa dà mọ ohun tó ń ṣe mí, wọ́n ní mo ti ní àrùn Lyme.

 Àrùn Lyme yìí ba àwọn iṣan tó ń bá ọpọlọ mi ṣiṣẹ́ jẹ́. Kódà nígbà míì, ṣe lara mi á kàn dédé máa gbọ̀n bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti ṣe díẹ̀ tí mo ti ń gbàtọ́jú. Ìgbà míì wà tí ara mi tàbí àwọn ìka mi á máa dùn mí gan-an débi pé mi ò ní lè lò ó. Àfi bíi pé àwọn oríkèé ara mi ti dógùn-ún.

 Mo máa ń rò ó pé, ‘Ṣó yẹ kírú àìsàn yìí máa ṣe ọmọdé ara mi?,’ ó sì máa ń múnú bí mi. Ojoojúmọ́ ni mo máa ń sunkún sí Ọlọ́run lọ́rùn pé, “Kí ni mo ṣe tírú ìyà yìí fi ń jẹ mí?” Ó tiẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe mí bíi pé Ọlọ́run ti gbàgbé mi. Àmọ́ mo rántí ìtàn Jóòbù nínú Bíbélì. Jóòbù ò mọ ohun tó fà á tóun fi ń kojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro, síbẹ̀ kò yẹ ìṣòtítọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run. Tí Jóòbù ò bá bọ́hùn pẹ̀lú adúrú ìṣòro tó ní, èmi náà lè ṣe é.

 Àwọn alàgbà inú ìjọ mi dúró tì mí gbágbáágbá. Wọn ò yé wá wò mí, kí wọ́n sì béèrè àlàáfíà mi. Alàgbà kan tiẹ̀ sọ fún mi pé kí n máa pe òun nígbàkigbà tí mo bá ń wẹ́ni tí mo lè bá sọ̀rọ̀, ìgbà yòówù kó jẹ́. Ojoojúmọ́ ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún mi nírú àwọn ọ̀rẹ́ báyìí!​—Aísáyà 32:​1, 2.

 Tá a bá ní àìsàn tá à ń bá fínra, a máa ń gbàgbé nígbà míì pé ohun tó ń ṣe wá ò pa mọ́ lójú Jèhófà, ó mọ ohun tójú wa ń rí. Bíbélì sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà, . . . yóò sì gbé ọ ró.” (Sáàmù 55:22) Ohun tí mo máa ń gbìyànjú láti ṣe lójoojúmọ́ nìyẹn.

 Ronú nípa èyí: Tó o bá ń ṣàìsàn tó le, báwo ni ohun táwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ bá ṣe ṣe lè jẹ́ kó o máa fara dà á?​—Òwe 24:10; 1 Tẹsalóníkà 5:​11.

 Nisa

 Mo ti lé lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nígbà tí wọ́n sọ fún mi pé mo ní àrùn Marfan syndrome, ìyẹn àrùn tó máa ń ba oríkèé ara jẹ́, tí kì í jẹ́ kó lágbára. Àrùn yìí tún máa ń fa ìrora níbi ọkàn, ojú àtàwọn ẹ̀yà ara míì tó ṣe pàtàkì. Ojoojúmọ́ kọ́ ni mo máa ń jẹ̀rora, àmọ́ tí ìrora ọ̀hún bá bẹ̀rẹ̀, bí iná ni.

 Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ sọ ohun tó ń ṣe mí fún mi, mo sunkún, ojú mi fẹ́rẹ̀ẹ́ yọ. Ìrònú bá mi pé mi ò ní lè ṣe gbogbo ohun tí mo fẹ́ràn láti máa ṣe mọ́. Bí àpẹẹrẹ, mo fẹ́ràn kí n máa jó. Mo rò ó pé bópẹ́bóyá, mi ò ní lè jó mọ́ torí ìrora, kódà, àti rìn lè di ìṣòro, ó wá ń mú kẹ́rù ibi táyé mi á yọrí sí máa bà mí.

 Àǹtí mi ò fi mí sílẹ̀. Àwọn ni ò jẹ́ kí n máa banú jẹ́. Wọ́n ní kí n gbé ìbẹ̀rù ohun tó lè ṣẹlẹ̀ kúrò lọ́kàn, torí kò ní jẹ́ kí n gbádùn ayé mi. Wọ́n tún rọ̀ mí pé kí n má dákẹ́ àdúrà, torí Jèhófà mọ gbogbo ohun tó ń ṣe mí, òun nìkan sì lọ̀rọ̀ mi yé dáadáa.​—1 Pétérù 5:7.

 Ẹsẹ Bíbélì kan tó máa ń gbé mi ró ni Sáàmù 18:6, tó sọ pé: “Mo ń ké pe Jèhófà ṣáá nínú wàhálà mi, mo sì ń kígbe sí Ọlọ́run mi fún ìrànlọ́wọ́. Ó bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ohùn mi láti inú tẹ́ńpìlì rẹ̀, igbe mi níwájú rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ sì dé etí rẹ̀.” Ẹsẹ Bíbélì yẹn jẹ́ kó yé mi pé tí mo bá gbàdúrà sí Jèhófà, tí mo sì bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kí n lè fara da ohun tó ń ṣe mí, ó máa gbọ́ mi, á sì ràn mí lọ́wọ́. Kò sígbà tí mo pè é tí kò ní dáhùn.

 Ohun tí mo ti kọ́ ni pé kò sóhun tó burú kéèyàn banú jẹ́ tàbí kí àjálù tó dé bá a tiẹ̀ kó ẹ̀dùn ọkàn bá a torí kò sẹ́ni tírú ẹ̀ ò lè ṣe. A ò kàn gbọ́dọ̀ wá jẹ́ kí ìbànújẹ́ yẹn gbà wá lọ́kàn tàbí kó ba àjọse tí àwa àti Ọlọ́run ní jẹ́, torí Ọlọ́run kọ́ ló ń fa ìṣòro bá wa. Ọlọ́run ò sì ní fi wá sílẹ̀ láé táwa náà ò bá ti fi sílẹ̀, tá ò jẹ́ kí nǹkan míì gba àyè Ọlọ́run lọ́kàn wa.​—Jákọ́bù 4:8.

 Ronú nípa èyí: Ṣe Ọlọ́run ló lẹ̀bi ìyà tó ń jẹ wá?​—Jákọ́bù 1:​13.