Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JW LIBRARY

Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè​—JW Library (Lórí Android)

Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè​—JW Library (Lórí Android)

Àwọn ètò ìṣiṣẹ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí ló lè bá JW Library ṣiṣẹ́:

  • Android 4.1 tàbí àwọn tó dé lẹ́yìn ẹ̀

  • iOS 9 tàbí àwọn tó dé lẹ́yìn ẹ̀

  • Windows 10 version 1709 tàbí àwọn tó dé lẹ́yìn ẹ̀

JW Library lè máa ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ àti nítorí ọ̀rọ̀ ààbò, a ò ní lè máa rí i lò lórí àwọn ètò ìṣiṣẹ́ tí ọjọ́ ẹ̀ ti pẹ́. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kàn, ó máa gba pé ká já àwọn ètò ìṣiṣẹ́ tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ sílẹ̀, tí wọ́n ò sì ní lè bá JW Library ṣiṣẹ́ mọ́. Torí náà, a rọ̀ ẹ́ pé kó máa rí i dájú pé ètò ìṣiṣẹ́ tó dé kẹ́yìn ló wà lórí ẹ̀rọ rẹ. Tí kò bá ṣeé ṣe fún ẹ láti fi ètò ìṣiṣẹ́ tó dé kẹ́yìn sórí ẹ̀rọ rẹ, wàá ṣì lè máa lo JW Library fún àwọn àkókò kan, àmọ́ oò ní ní JW Library tó dé kẹ́yìn.

 

Díẹ̀díẹ̀ làwọn èdè tuntun máa ń débẹ̀. Tó o bá fẹ́ rí àwọn èdè tí ìtẹ̀jáde kan wà, tẹ Èdè.

Àwọn àwọ̀ yìí máa jẹ́ ká lóye ọ̀nà mẹ́jọ tá a lè pín àwọn ìwé inú Bíbélì sí, bá a ṣe ṣàlàyé ẹ̀ ní Ìbéèrè 19 nínú Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

 

Orí àwọn fóònù tó jẹ́ Android 4.0 sókè nìkan ni Bíbélì Kingdom Interlinear ti lè ṣiṣẹ́.

 

Bákan náà ni àwọn ohun tó wà lórí JW Library ṣe ń ṣiṣẹ́ lórí Android, iOS àti Windows. Àmọ́ ìgbà tí nǹkan tuntun máa ń dórí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lè yàtọ̀ síra.

 

Bẹ́ẹ̀ ni. O lè tọ́jú àwọn ọ̀rọ̀ tó o kọ, àwọn ohun tó o yàn láàyò àtàwọn ohun tó o sàmì sí. Tó bá yá, o lè gbé gbogbo ẹ̀ pa dà sórí fóònù ẹ tàbí sọ́rí fóònù míì látibi tó o tọ́jú ẹ̀ sí.

 

Rárá. Ní báyìí ná, o ò tíì lè lo àwọn ọ̀rọ̀ tó o kọ, ohun tó o yàn láàyò àtàwọn ohun tó o sàmì sí lórí fóònù méjì lẹ́ẹ̀kan náà.

 

Ìṣòro: Lẹ́yìn tó o wa JW Library tó dé kẹ́yìn sórí ẹ̀rọ rẹ, o lè ṣàkíyèsí pé ṣe ni o ò rí gbogbo àwọn ohun tó o ti kọ sórí JW Library àti àwọn ohun tó o fi àmì sí mọ́. O ò rí àwọn ohun tó o kọ, àwọn ohun tó o fi àmì sí àti àwọn ohun tó o kùn lọ́dà mọ́.

Ojútùú: Tó o bá lọ wa JW Library tó dé lẹ́yìn ìyẹn jáde, ó ṣeéṣe kó yanjú ìṣòro náà. Lọ wa èyí tó dé kẹ́yìn jáde, kó o wá tẹ̀ lé àwọn ìsọfúnni tó gbé sójú bó ṣe ń fi sí orí ẹ̀rọ rẹ, kó o lè dá gbogbo àwọn ohun tó o ti kọ síbẹ̀ tẹ́lẹ̀ pa dà.

 

O lè ní kí ẹnì kan tó mọ ètò JW Library lò dáadáa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tí kò bá sí ẹni tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́, jọ̀wọ́ kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó sún mọ́ ẹ jù lọ.