Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JW LIBRARY

Bó O Ṣe Lè Wa Ìwé Jáde Kó O sì Máa Lò Ó​—Lórí Android

Bó O Ṣe Lè Wa Ìwé Jáde Kó O sì Máa Lò Ó​—Lórí Android

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ńlá, ìwé pẹlẹbẹ àtàwọn àṣàrò kúkúrú ló wà tó o lè kà lórí JW Library, àwọn fídíò tó o sì lè wò wà níbẹ̀.

Tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí kó o lè wa àwọn ìwé jáde, kó o sì máa lò ó:

 Wa Ìwé Jáde

Ìwé pọ̀ gan-an tó o lè wà jáde láti máa kà, kó o sì máa kẹ́kọ̀ọ́.

  • Fìka fa apá òsì lọ́wọ́ òkè ojú fóònù ẹ, kó o tẹ Publications kó o lè rí àwọn ìwé tó wà.

  • Tẹ bọ́tìnì Èdè kó o lè rí gbogbo èdè tí ìwé wà. Yan èdè tó o fẹ́. Àwọn èdè tó o bá ń lò jù ló sábà máa ń wà lókè pátápátá. O tún lè fi orúkọ èdè kan wá èdè náà.

Oríṣiríṣi ọ̀nà lo lè fi wá ìwé lórí n JW Library.

Ní apá tá a pè ní By Type, wàá rí àwọn ìwé ní èdè tó ò ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́, a tò wọ́n ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, bí Ìwé Ńlá, Àṣàrò Kúkúrú tàbí Fídíò. Tó o bá tẹ ìsọ̀rí kan, á tún gbé àwọn ìsọ̀rí kéékèèké míì wá fún ẹ. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá tẹ The Watchtower, ó máa gbé oríṣiríṣi ọdún wá fún ẹ, tó bá sì jẹ́ Fídíò ni, ó máa gbé oríṣiríṣi ìsọ̀rí tó pín sí wá. Tó o bá fẹ́ pa dà síbẹ̀rẹ̀, o lè tẹ All Types.

Apá tá a pè ní What’s New máa jẹ́ kó o rí àwọn ìwé tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde ní èdè tó ò ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́.

Wàá rí àmì òfúrufú lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ìwé tó ò tíì wà jáde. Tẹ ìwé kan kó o lè wà á jáde. Tí ìwé náà bá ti dórí fóònù ẹ, o ò ní rí àmì òfúrufú yẹn níbẹ̀ mọ́. Tún tẹ ìwé náà kó o lè kà á.

Ní apá tá a pè ní Downloaded, wàá rí gbogbo ìwé tó o ti wà jáde, èdè yòówù kó jẹ́. O lè ṣe é kó fi àwọn ìsọ̀rí bíi Frequently Used, Rarely Used tàbí Largest Size tò wọ́n.

 Yọ Ìwé Kúrò

O lè yọ ìwé kan kúrò tó ò bá fẹ́ mọ́, tàbí tí fóònù ẹ ti kún, tó o sì fẹ́ kí àyè wà lórí ẹ̀.

Fìka fa apá òsì lọ́wọ́ òkè ojú fóònù ẹ, kó o tẹ Publications, kó o wá tẹ ìsọ̀rí kan (bí àpẹẹrẹ, Books) kó o lè rí àwọn ìwé tó wà níbẹ̀. Tẹ àmì tó-tò-tó tó wà lórí ìwé tó o fẹ́ yọ kúrò, kó o wá tẹ Delete.

Tó o bá fẹ́ kí àyè wà lórí fóònù ẹ, o lè yọ àwọn ìwé tó ò kì í sábà lò tàbí àwọn tó tóbi gan-an kúrò. Fìka fa apá òsì lọ́wọ́ òkè ojú fóònù ẹ, kó o wá tẹ Publications. Lọ sí Downloaded, kó o wá yan Rarely Used àbí Largest Size kó o lè tún un tò. Lẹ́yìn náà, yọ àwọn ìwé tó ò bá fẹ́ kúrò.

 Wa Ìwé Tá A Tún Ṣe Jáde

Látìgbà dégbà, a lè máa ṣe àtúnṣe sí àwọn ìwé kan tó o ti wà jáde tẹ́lẹ̀.

Tí àtúnṣe bá ti wà lórí ìwé kan, wàá rí àmì róbóróbó kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Tó o bá ti tẹ ìwé yẹn, o máa rí ìsọfúnni pé àtúnṣe ti wà. Wá tẹ Download kó o lè tún un wà jáde, tàbí kó o tẹ Later kó o lè máa ka èyí tó o ti ní lọ́wọ́ tẹ́lẹ̀ lọ.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ bóyá àwọn ìwé tó o ti wà jáde tẹ́lẹ̀ ní àtúnṣe, fìka fa apá òsì lọ́wọ́ òkè ojú fóònù ẹ, kó o wá tẹ Publications. Tí àtúnṣe kankan bá wà, wàá rí apá kan tá a pè ní Pending Updates. Tẹ̀ ẹ́ kó o lè rí gbogbo àwọn ìtẹ̀jáde tó ti ní àtúnṣe. Tẹ ìwé kan kó o lè tún un wà jáde, tàbí kó o tẹ Update All kó lè wa gbogbo ìwé tó ti ní àtúnṣe jáde.

February 2015 la gbé àwọn àtúnṣe yìí jáde, ó bá JW Library 1.4 wá. Ó máa ṣiṣẹ́ lórí Android 2.3 sókè. Tó ò bá rí i lórí fóònù ẹ, jọ̀ọ́ tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú àpilẹ̀kọ “Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Lo JW Library​—Lórí Android,” lábẹ́ Rí Àwọn Ohun Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé.