Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JW LIBRARY

Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Lo JW Library​—Windows

Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Lo JW Library​—Windows

Káàbọ̀ sórí JW Library. A ṣe ètò ìṣiṣẹ́ yìí láti máa fi ka Bíbélì, ká sì máa fi kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Tó o bá fẹ́ rí àwọn ohun pàtàkì tó wà lórí rẹ̀, tẹ àwọn bọ́tìnì tó wà nísàlẹ̀ abala ìbẹ̀rẹ̀. Tó o bá fẹ́ ṣí àpótí tá a pè ní App Commands, tẹ bọ́tìnì apá ọ̀tún lórí mouse rẹ tàbí kó o fìka fa ojú fóònù rẹ wálẹ̀ látòkè pátápátá.

 Home

Apá tá a pè ní Home máa jẹ́ kó o tètè rí Bíbélì àtàwọn ìwé tó o máa ń lò jù. Wàá tún rí àwọn ìwé tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé àti ẹsẹ ojúmọ́ tòní níbẹ̀.

 Bible

Apá tá a pè ní Bible máa jẹ́ kó o lè ka Bíbélì, kó o sì wa àwọn ìtumọ̀ Bíbélì jáde. Tó o bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì, tẹ ìwé Bíbélì kan, kó o wá tẹ orí tó o fẹ́ kà. Bó o ṣe ń kà á, wàá tún máa rí àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, atọ́ka àtàwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì ní abala Ìkẹ́kọ̀ọ́ lápá ọ̀tún.

Tó o bá fẹ́ wo ẹsẹ Bíbélì míì, pa dà sí Bible kó o lè pa dà rí ibi tá a to àwọn ìwé Bíbélì sí.

 Publications

Apá tá a pè ní Publications máa jẹ́ kó o rí àwọn ìwé, àtẹ́tísí àti fídíò. Tó o bá fẹ́ kàwé, tẹ ìwé kan, kó o sì tẹ àpilẹ̀kọ kan níbẹ̀. Bó o ṣe ń kàwé, o tún lè máa wo àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀. Tó o bá tẹ ẹsẹ Bíbélì tó o fẹ́ kà, wàá rí i ní abala Ìkẹ́kọ̀ọ́. Tẹ ìlujá ẹsẹ Bíbélì kan ní abala Ìkẹ́kọ̀ọ́, ó máa gbé ẹ lọ sínú Bíbélì gangan.

Tó o bá fẹ́ ṣí ìtẹ̀jáde míì, tẹ Publications, kó o wá tẹ By Type kó o lè pa dà sí ibi táwọn ìtẹ̀jáde wà.

 Daily Text

Níbi àpótí tó wà lókè lójú fóònù ẹ, tẹ Daily Text kó o lè rí ẹsẹ ojúmọ́ tòní.

 Online

Níbi àpótí tó wà lókè lójú fóònù ẹ, tẹ Online kó o lè rí ìlujá tó máa gbé ẹ lọ sórí àwọn ìkànnì wa.

 Rí Àwọn Ohun Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé

Máa rí i pé ètò ìṣiṣẹ́ Windows tó dé kẹ́yìn ló wà lórí fóònù ẹ kó o lè máa rí ohun tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sórí JW Library.

Ó dáa kó jẹ́ pé ètò ìṣiṣẹ́ Windows tó dé kẹ́yìn lò ń lò lórí fóònù ẹ. Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i, tẹ àwọn ìlujá yìí:

For your convenience, you can turn on automatic app updates in your device settings. See the following link for more information: http://windows.microsoft.com/en-gb/windows-8/automatic-app-updates-help.