Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JW LIBRARY

Wá Ọ̀rọ̀ Nínú Bíbélì Tàbí Nínú Ìwé​—Lórí Windows

Wá Ọ̀rọ̀ Nínú Bíbélì Tàbí Nínú Ìwé​—Lórí Windows

Ohun tá a fi ń wá ọ̀rọ̀ nínú JW Library máa jẹ́ kó o lè wá ọ̀rọ̀ nínú Bíbélì tàbí nínú ìwé.

Tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí kó o lè wá ọ̀rọ̀:

 Wá Ọ̀rọ̀ Nínú Bíbélì

O lè wá ọ̀rọ̀ nínú Bíbélì tó ò ń kà lọ́wọ́.

Tó o bá ti ṣí Bíbélì, tẹ Search, kó o wá tẹ ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ wá síbẹ̀. Bó o bá ṣe ń tẹ̀ ẹ́, ó máa gbé oríṣiríṣi àbá wá fún ẹ. Yan ọ̀kan lára àwọn àbá náà tàbí kó o tẹ bọ́tìnì Enter lórí keyboard, ó máa gbé èsì wá fún ẹ.

Top Verses máa jẹ́ kó o rí àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a sábà máa ń lò tó bá ọ̀rọ̀ tó ò ń wá mu. All Verses máa jẹ́ kó o rí gbogbo ẹsẹ Bíbélì tó bá ọ̀rọ̀ tó ò ń wá mu, á sì tò ó bí àwọn ìwé inú Bíbélì ṣe tò tẹ̀ léra. Articles máa jẹ́ kó o rí àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ àtàwọn àfikún.

Tó bá jẹ́ ọ̀rọ̀ tó ju eyọ kan lọ lo tẹ̀, yan àpótí Match Exact Phrase kó o lè rí ẹsẹ Bíbélì tàbí àpilẹ̀kọ tó bá àwọn ọ̀rọ̀ tó o tẹ̀ mu gẹ́lẹ́.

 Wá Ọ̀rọ̀ Nínú Ìwé

O lè wá ọ̀rọ̀ nínú ìwé tó ò ń kà lọ́wọ́.

Tó o bá ti ṣí ìwé kan, tẹ Search, kó o wá tẹ ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ wá síbẹ̀. Bó o bá ṣe ń tẹ̀ ẹ́, ó máa gbé oríṣiríṣi àbá wá fún ẹ. Yan ọ̀kan lára àwọn àbá náà tàbí kó o tẹ bọ́tìnì Enter lórí keyboard, ó máa gbé èsì wá fún ẹ.

Tó bá jẹ́ ọ̀rọ̀ tó ju eyọ kan lọ lo tẹ̀, yan àpótí Match Exact Phrase kó o lè rí ẹsẹ Bíbélì tàbí àpilẹ̀kọ tó bá àwọn ọ̀rọ̀ tó o tẹ̀ mu gẹ́lẹ́.

 Wá Àkòrí Ọ̀rọ̀ Kan

Tó o bá ti wa ìwé Insight on the Scriptures jáde sórí fóònù ẹ, o lè wá àkòrí ọ̀rọ̀ kan nínú ìwé náà. Wàá lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá ń ka Bíbélì tàbí ìwé èyíkéyìí nínú JW Library.

Tẹ Search, kó o wá tẹ àkòrí ọ̀rọ̀ tó ò ń wá. Bó o ṣe ń tẹ̀ ẹ́, wàá rí àwọn àkòrí tó bá a mu nínú ìwé Insight on the Scriptures nínú àwọn àbá tó máa gbé wá. Tẹ àkòrí ọ̀rọ̀ kan kó o lè ṣí àpilẹ̀kọ náà.

October 2014 la gbé àwọn àtúnṣe yìí jáde, ó bá JW Library 1.3.4 wá. Ó máa ṣiṣẹ́ lórí Windows 8.0 sókè. Tó ò bá rí i lórí fóònù ẹ, jọ̀ọ́ tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú àpilẹ̀kọ “Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Lo JW Library​—Lórí Windows,” lábẹ́ Rí Àwọn Ohun Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé.